28 wọ́n sanra, ara wọn sì ń dán.Ṣugbọn iṣẹ́ ibi wọn kò ní ààlà.Wọn kìí dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún aláìníbaba,kí ó lè rí ẹ̀tọ́ rẹ̀ gbà;wọn kò sì jẹ́ gbèjà aláìní,kí wọ́n bá a dáàbò bo ẹ̀tọ́ rẹ̀ nílé ẹjọ́.
29 Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?Kí n má gbẹ̀san ara mi, lára irú orílẹ̀-èdè yìí?
30 Nǹkan burúkú tó yani lẹ́nu,ní ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà:
31 Àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké,àwọn alufaa ń sọ ọ̀rọ̀ èké àwọn wolii di òfin,àwọn eniyan mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.Ṣugbọn kí ni wọ́n óo ṣe nígbà tí òpin bá dé?”