Jeremaya 5:3-9 BM

3 OLUWA, ṣebí òtítọ́ ni ò ń fẹ́?Ò ń nà wọ́n ní pàṣán, ṣugbọn kò dùn wọ́n,o tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́,ṣugbọn wọn kò gbọ́ ìbáwí.Ojú wọn ti dá, ó le koko,wọ́n kọ̀, wọn kò ronupiwada.

4 Nígbà náà ní mo wí lọ́kàn ara mi pé,“Àwọn aláìní nìkan nìwọ̀nyí,wọn kò gbọ́n;nítorí wọn kò mọ ọ̀nà OLUWA,ati òfin Ọlọrun wọn.

5 N óo lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan pataki pataki,n óo sì bá wọn sọ̀rọ̀;nítorí àwọn mọ ọ̀nà OLUWA,ati òfin Ọlọrun wọn.”Ṣugbọn gbogbo wọn náà ni wọ́n ti fa àjàgà wọn dá,tí wọ́n sì ti kọ àṣẹ ati àkóso OLUWA.

6 Nítorí náà, kinniun inú igbó ni yóo wá kì wọ́n mọ́lẹ̀.Ìkookò inú aṣálẹ̀ ni yóo wá jẹ wọ́n run.Àmọ̀tẹ́kùn yóo ba dè wọ́n ní àwọn ìlú wọn,tí ẹnikẹ́ni bá jáde ní ìlú,yóo fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀,nígbà pupọ ni wọ́n sì ti yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun.

7 OLUWA bi Israẹli pé,“Báwo ni mo ṣe lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn ọ́?Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀,wọ́n sì ti ń fi àwọn ohun tí kì í ṣe ọlọrun búra.Nígbà tí mo bọ́ wọn ní àbọ́yó tán,wọ́n ṣe àgbèrè,wọ́n dà lọ sí ilé àwọn alágbèrè.

8 Wọ́n dàbí akọ ẹṣin tí a kò tẹ̀ lọ́dàá, tí ó yó,olukuluku wọn ń lé aya aládùúgbò rẹ̀ kiri.

9 Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?