9 Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?
10 Kọjá lọ láàrin ọgbà àjàrà rẹ̀ ní poro ní poro, kí o sì pa á run,ṣugbọn má ṣe pa gbogbo rẹ̀ run tán.Gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,nítorí pé wọn kì í ṣe ti OLUWA.
11 Nítorí pé ilé Israẹli ati ilé Juda ti ṣe alaiṣootọ sí mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
12 Àwọn eniyan yìí ti sọ ọ̀rọ̀ èké nípa OLUWA,wọ́n ní, “OLUWA kọ́! Kò ní ṣe nǹkankan;ibi kankan kò ní dé bá wa,bẹ́ẹ̀ ni a kò ní rí ogun tabi ìyàn.”
13 Àwọn wolii yóo di àgbá òfo;nítorí kò sí ọ̀rọ̀ OLUWA ninu wọn.Bí wọ́n ti wí ni ọ̀rọ̀ yóo rí fún wọn.
14 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní,“Nítorí ohun tí wọ́n sọ yìí,wò ó, n óo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi di iná lẹ́nu rẹ.N óo sì jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi dàbí igi,iná yóo sì jó wọn run.
15 Ẹ wò ó, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli,mò ń mú orílẹ̀-èdè kan bọ̀ wá ba yín, láti ilẹ̀ òkèèrè,tí yóo ba yín jà.Láti ayé àtijọ́ ni orílẹ̀-èdè ọ̀hún ti wà,orílẹ̀-èdè alágbára ni.Ẹ kò gbọ́ èdè wọn,ẹ kò sì ní mọ ohun tí wọ́n ń sọ.