1 OLUWA ní,“Wò ó! N óo gbé ẹ̀mí apanirun kan dìde sí Babiloni,ati sí àwọn ará Kalidea;
2 n óo rán ìjì líle kan sí Babiloni,ìjì náà yóo fẹ́ ẹ dànù bí ìyàngbò ọkàyóo sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro,nígbà tí wọ́n bá gbógun tì í yípo, ní ọjọ́ ìpọ́njú.
3 Kí tafàtafà má kẹ́ ọrun rẹ̀,kí ó má sì gbé ẹ̀wù irin rẹ̀ wọ̀.Má ṣe dá àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ sí,pa gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ run patapata.
4 Kí wọ́n ṣubú, kí wọ́n sì kú ní ilẹ̀ Kalidea,kí wọ́n gún wọn ní àgúnyọ láàrin ìgboro.
5 Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ati Juda kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀;ṣugbọn ilẹ̀ Kalidea kún fún ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀,tí wọ́n dá sí Ẹni Mímọ́ Israẹli.
6 Ẹ sá kúrò láàrin Babiloni,kí olukuluku sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀!Ẹ má parun nítorí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ Babiloni;nítorí àkókò ẹ̀san OLUWA nìyí,yóo sì san ẹ̀san fún Babiloni.