17 Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan, wọn kò sì ní ìmọ̀,gbogbo alágbẹ̀dẹ wúrà sì gba ìtìjú lórí oriṣa tí wọn dà;nítorí pé irọ́ ni ère tí wọ́n rọ,wọn kò ní èémí.
18 Asán ni wọ́n, wọ́n ń ṣini lọ́nà,píparun ni wọn yóo parun, ní ọjọ́ ìjìyà wọn.
19 Ọlọrun ti Jakọbu kò dàbí àwọn wọnyi,nítorí pé òun ní ẹlẹ́dàá ohun gbogbo;ẹ̀yà Israẹli ni eniyan tirẹ̀,OLUWA àwọn ọmọ ogun sì ni orúkọ rẹ̀.OLUWA sọ fún Babiloni pé,
20 “Ìwọ ni òòlù ati ohun ìjà mi:ìwọ ni mo fi wó àwọn orílẹ̀-èdè wómúwómú,ìwọ ni mo sì fi pa àwọn ìjọba run.
21 Ìwọ ni mo fi lu ẹṣin ati ẹni tí ń gùn ún pa;ìwọ ni mo fi wó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn tí ń bẹ ninu wọn.
22 Ìwọ ni mo fi lu tọkunrin tobinrin pa,ìwọ ni mo fi lu tọmọde, tàgbà pa,ìwọ ni mo sì fi run àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin.
23 Ìwọ ni mo fi pa olùṣọ́-aguntan ati agbo ẹran rẹ̀ rẹ́,ìwọ ni mo fi run àgbẹ̀ ati àwọn alágbàro rẹ̀,ìwọ ni mo fi ṣẹ́ apá àwọn gomina ati ti àwọn olórí ogun.”