50 OLUWA sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ ní Babiloni pé,“Ẹ̀yin tí ẹ bọ́ lọ́wọ́ idà,ẹ má dúró, ẹ máa sálọ!Ẹ ranti OLUWA ní ilẹ̀ òkèèrè,kí ẹ sì máa ronú nípa Jerusalẹmu pẹlu.
51 Ẹ̀ ń sọ pé ojú ń tì yín nítorí pé wọ́n kẹ́gàn yín;ẹ ní ìtìjú dà bò yín,nítorí pé àwọn àjèjì ti wọ ibi mímọ́ ilé OLUWA.
52 Nítorí náà, èmi OLUWA ń sọ nisinsinyii pé,ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ère rẹ̀;àwọn tí wọ́n fara gbọgbẹ́ yóo máa kérora,ní gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.
53 Bí Babiloni tilẹ̀ ga tí ó kan ojú ọ̀run,tí ó sì mọ odi yí àwọn ibi ààbò rẹ̀ gíga ká,sibẹsibẹ n óo rán apanirun sí i.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
54 OLUWA ní,“Ẹ gbọ́ igbe kan láti Babiloni!Igbe ìparun ńlá láti ilẹ̀ àwọn ará Kalidea!
55 Nítorí OLUWA ń wó Babiloni lulẹ̀,ó sì ń pa á lẹ́nu mọ́.Igbe wọn ta sókè bíi híhó omi òkun ńlá
56 nítorí pé apanirun ti dé sí i,àní ó ti dé sí Babiloni.Ogun ti kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀,àwọn ọ̀tá ti rún àwọn ọfà rẹ̀ jégéjégé,nítorí pé Ọlọrun ẹ̀san ni èmi OLUWA,dájúdájú n óo gbẹ̀san.