51 Ẹ̀ ń sọ pé ojú ń tì yín nítorí pé wọ́n kẹ́gàn yín;ẹ ní ìtìjú dà bò yín,nítorí pé àwọn àjèjì ti wọ ibi mímọ́ ilé OLUWA.
52 Nítorí náà, èmi OLUWA ń sọ nisinsinyii pé,ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ère rẹ̀;àwọn tí wọ́n fara gbọgbẹ́ yóo máa kérora,ní gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.
53 Bí Babiloni tilẹ̀ ga tí ó kan ojú ọ̀run,tí ó sì mọ odi yí àwọn ibi ààbò rẹ̀ gíga ká,sibẹsibẹ n óo rán apanirun sí i.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
54 OLUWA ní,“Ẹ gbọ́ igbe kan láti Babiloni!Igbe ìparun ńlá láti ilẹ̀ àwọn ará Kalidea!
55 Nítorí OLUWA ń wó Babiloni lulẹ̀,ó sì ń pa á lẹ́nu mọ́.Igbe wọn ta sókè bíi híhó omi òkun ńlá
56 nítorí pé apanirun ti dé sí i,àní ó ti dé sí Babiloni.Ogun ti kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀,àwọn ọ̀tá ti rún àwọn ọfà rẹ̀ jégéjégé,nítorí pé Ọlọrun ẹ̀san ni èmi OLUWA,dájúdájú n óo gbẹ̀san.
57 N óo jẹ́ kí àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ mu ọtí ní àmuyó,pẹlu àwọn gomina rẹ̀, àwọn ọ̀gágun rẹ̀, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀.Wọn yóo sun oorun àsùnrayè,wọn kò sì ní jí mọ́ laelae.Bẹ́ẹ̀ ni èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ.