1 Ẹ̀yin ọmọ Bẹnjamini, ẹ sá àsálà!Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu.Ẹ fọn fèrè ogun ní Tekoa,kí ẹ ṣe ìkìlọ̀ fún wọn ní Beti Hakikeremu,nítorí pé nǹkan burúkúati ìparun ńlá ń bọ̀ láti ìhà àríwá.
2 Jerusalẹmu, Ìlú Sioni dára, ó sì lẹ́wà,ṣugbọn n óo pa á run.
3 Àwọn ọba ati àwọn ọmọ ogun wọn yóo kọlù ú,wọn yóo pa àgọ́ yí i ká,ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan yóo pàgọ́ sí ibi tí ó wù ú.
4 Wọn yóo sì wí pé, “Ẹ múra kí á bá a jagun;ẹ dìde kí á lè kọlù ú lọ́sàn-án gangan!”Wọn óo tún sọ pé, “A gbé! Nítorí pé ọjọ́ ti lọ,ilẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣú!