Jeremaya 6:5-11 BM

5 Ẹ dìde kí á lè kọlù ú, lóru;kí á wó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀!”

6 Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀tá pé:“Ẹ gé àwọn igi tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀;kí ẹ fi mọ òkítì kí ẹ sì dótì í.Dandan ni kí n fi ìyà jẹ ìlú náà,nítorí kìkì ìwà ìninilára ló kún inú rẹ̀.

7 Bí omi ṣé ń sun jáde ninu kànga,bẹ́ẹ̀ ni ibi ń sun ní Jerusalẹmu.Ìròyìn ìwà ipá ati ti jàgídíjàgan ń kọlura wọn ninu rẹ̀,àìsàn ati ìpalára ni à ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo.

8 Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ tí mò ń ṣe fun yín,bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi pẹlu yín óo pínyà,n óo sì sọ Jerusalẹmu di ahoro,ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé ibẹ̀ mọ́.”

9 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:“Ẹ ṣa àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ,bí ìgbà tí eniyan bá ń ṣa èso àjàrà tókù lẹ́yìn ìkórè.Tún dá ọwọ́ pada sẹ́yìn, kí o fi wọ́ ara àwọn ẹ̀ka,bí ẹni tí ń ká èso àjàrà.”

10 Mo ní, “Ta ni kí n bá sọ̀rọ̀, tí yóo gbọ́?Ta ni kí n kìlọ̀ fún tí yóo gbà?Etí wọn ti di, wọn kò lè gbọ́ràn mọ́.Ọ̀rọ̀ OLUWA ń rùn létí wọn,wọn kò fẹ́ gbọ́ mọ́.

11 Ibinu ìwọ OLUWA mú kí inú mi máa ru,ara mi kò sì gbà á mọ́.”OLUWA bá sọ fún mi pé,“Tú ibinu mi dà sórí àwọn ọmọde ní ìta gbangba,ati àwọn ọdọmọkunrin níbi tí wọ́n péjọ sí.Ogun yóo kó wọn, tọkọtaya,àtàwọn àgbàlagbà àtàwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́.