13 “Ní àkókò ìkórè, kò ní sí èso lórí àjàrà,igi ọ̀pọ̀tọ́ kò ní ní èso lórí,àwọn ewé pàápàá yóo gbẹ,ohun tí mo fún wọn yóo di ti ẹlòmíràn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
14 Àwọn eniyan Ọlọrun bá dáhùn pé,“Kí ló dé tí a fi jókòó jẹ̀kẹ̀tẹ̀?Ẹ jẹ́ kí á kó ara wa jọ,kí á sá lọ sí àwọn ìlú olódi,kí á sì parun sibẹ;nítorí OLUWA Ọlọrun wa ti fi wá lé ìparun lọ́wọ́,ó ti fún wa ní omi tí ó ní májèlé mu,nítorí pé a ti ṣẹ̀ ẹ́.
15 À ń retí alaafia,ṣugbọn ire kankan kò dé.Àkókò ìwòsàn ni à ń retí,ṣugbọn ìpayà ni a rí.
16 Ẹ gbọ́ bí ẹṣin wọn tí ń fọn imú, ní ilẹ̀ Dani;gbogbo ilẹ̀ ń mì tìtì nítorí ìró yíyan ẹṣin wọn.Wọ́n wá run ilẹ̀ náà,ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,ati ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.”
17 OLUWA ní, “Wò ó! N óo rán ejò sí ààrin yín:paramọ́lẹ̀ tí kò ní gbóògùn;wọn yóo sì bù yín jẹ.”
18 Ìbànújẹ́ mi pọ̀ kọjá ohun tí ó ṣe é wòsàn,àárẹ̀ mú ọkàn mi.
19 Ẹ gbọ́ igbe àwọn eniyan mijákèjádò ilẹ̀ náà tí wọn ń bèèrè pé,“Ṣé OLUWA kò sí ní Sioni ni?Tabi ọba rẹ̀ kò sí ninu rẹ̀ ni?”OLUWA, ọba wọn dáhùn pé,“Kí ló dé tí wọn ń fi ère wọn mú mi bínú,pẹlu àwọn oriṣa ilẹ̀ àjèjì tí wọn ń bọ?”