14 Àwọn eniyan Ọlọrun bá dáhùn pé,“Kí ló dé tí a fi jókòó jẹ̀kẹ̀tẹ̀?Ẹ jẹ́ kí á kó ara wa jọ,kí á sá lọ sí àwọn ìlú olódi,kí á sì parun sibẹ;nítorí OLUWA Ọlọrun wa ti fi wá lé ìparun lọ́wọ́,ó ti fún wa ní omi tí ó ní májèlé mu,nítorí pé a ti ṣẹ̀ ẹ́.
15 À ń retí alaafia,ṣugbọn ire kankan kò dé.Àkókò ìwòsàn ni à ń retí,ṣugbọn ìpayà ni a rí.
16 Ẹ gbọ́ bí ẹṣin wọn tí ń fọn imú, ní ilẹ̀ Dani;gbogbo ilẹ̀ ń mì tìtì nítorí ìró yíyan ẹṣin wọn.Wọ́n wá run ilẹ̀ náà,ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,ati ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.”
17 OLUWA ní, “Wò ó! N óo rán ejò sí ààrin yín:paramọ́lẹ̀ tí kò ní gbóògùn;wọn yóo sì bù yín jẹ.”
18 Ìbànújẹ́ mi pọ̀ kọjá ohun tí ó ṣe é wòsàn,àárẹ̀ mú ọkàn mi.
19 Ẹ gbọ́ igbe àwọn eniyan mijákèjádò ilẹ̀ náà tí wọn ń bèèrè pé,“Ṣé OLUWA kò sí ní Sioni ni?Tabi ọba rẹ̀ kò sí ninu rẹ̀ ni?”OLUWA, ọba wọn dáhùn pé,“Kí ló dé tí wọn ń fi ère wọn mú mi bínú,pẹlu àwọn oriṣa ilẹ̀ àjèjì tí wọn ń bọ?”
20 Àwọn eniyan ní, “Ìkórè ti parí,àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn ti kọjá,sibẹ a kò rí ìgbàlà.”