18 Ìbànújẹ́ mi pọ̀ kọjá ohun tí ó ṣe é wòsàn,àárẹ̀ mú ọkàn mi.
19 Ẹ gbọ́ igbe àwọn eniyan mijákèjádò ilẹ̀ náà tí wọn ń bèèrè pé,“Ṣé OLUWA kò sí ní Sioni ni?Tabi ọba rẹ̀ kò sí ninu rẹ̀ ni?”OLUWA, ọba wọn dáhùn pé,“Kí ló dé tí wọn ń fi ère wọn mú mi bínú,pẹlu àwọn oriṣa ilẹ̀ àjèjì tí wọn ń bọ?”
20 Àwọn eniyan ní, “Ìkórè ti parí,àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn ti kọjá,sibẹ a kò rí ìgbàlà.”
21 Nítorí ọgbẹ́ àwọn eniyan mi ni ọkàn mi ṣe gbọgbẹ́.Mò ń ṣọ̀fọ̀, ìdààmú sì bá mi.
22 Ṣé kò sí ìwọ̀ra ní Gileadi ni?Àbí kò sí oníwòsàn níbẹ̀?Kí ló dé tí àìsàn àwọn eniyan mi kò sàn?