Jeremaya 8:6-12 BM

6 Mo tẹ́tí sílẹ̀ kí n gbọ́ tiwọn,ṣugbọn wọn kò sọ̀rọ̀ rere.Kò sí ẹni tí ó kẹ́dùn iṣẹ́ ibi rẹ̀,kí ó wí pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’Olukuluku tẹ̀ sí ọ̀nà tí ó wù ú,bí ẹṣin tí ń sáré lọ ojú ogun.

7 Ẹyẹ àkọ̀ tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá mọ àkókò rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ sì ni àdàbà, ati lékèélékèé, ati alápàáǹdẹ̀dẹ̀;wọ́n mọ àkókò tí ó yẹ láti ṣípò pada.Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò mọ òfin OLUWA.

8 Báwo ni ẹ ṣe lè wí pé,‘Ọlọ́gbọ́n ni wá,a sì mọ òfin OLUWA?’Ṣugbọn àwọn akọ̀wé ti fi gègé irọ́ wọn sọ ọ́ di èké.

9 Ojú yóo ti àwọn ọlọ́gbọ́n:ìdààmú yóo bá wọn,ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.Wò ó! Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀,ọgbọ́n wo ni ó kù tí wọ́n gbọ́n?

10 Nítorí náà, n óo fi aya wọn fún ẹlòmíràn,n óo fi oko wọn fún àwọn tí yóo ṣẹgun wọn.Nítorí pé láti orí àwọn mẹ̀kúnnù,títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki,gbogbo wọn ni wọ́n ń lépa èrè àjẹjù.Láti orí wolii títí kan alufaa, èké ni gbogbo wọn.

11 Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jinná,wọ́n ń kígbe pé, ‘Alaafia ni, alaafia ni,’bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí alaafia.

12 Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́nnígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́?Rárá o, ojú kì í tì wọ́n,nítorí pé wọn kò lójútì.Nítorí náà àwọn náà óo ṣubúnígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú,a óo bì wọ́n ṣubúnígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà,OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.