21 Nítorí ikú ti dé ojú fèrèsé wa,ó ti wọ ààfin wa.Ikú ń pa àwọn ọmọde nígboro,ati àwọn ọdọmọkunrin ní gbàgede.”
22 Sọ wí pé,“Òkú eniyan yóo sùn lọ nílẹ̀ bí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí pápá tí ó tẹ́jú,ati bíi ìtí ọkà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń kórè ọkà,kò sì ní sí ẹni tí yóo kó wọn jọ. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”
23 OLUWA ní, “Kí ọlọ́gbọ́n má fọ́nnu nítorí ọgbọ́n rẹ̀,kí alágbára má fọ́nnu nítorí agbára rẹ̀;kí ọlọ́rọ̀ má sì fọ́nnu nítorí ọrọ̀ rẹ̀.
24 Ṣugbọn ẹni tí ó bá fẹ́ fọ́nnu,ohun tí ó lè máa fi fọ́nnu ni pé òun ní òyeati pé òun mọ̀ pé, èmi OLUWA ni OLUWA tí ń ṣe ẹ̀tọ́,tí sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òdodo hàn lórí ilẹ̀ ayé;nítorí pé àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni mo ní inú dídùn sí.”
25 Ó ní, “Ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo fìyà jẹ àwọn tí a kọ nílà, ṣugbọn tí wọn ń ṣe bí aláìkọlà,
26 àwọn ará Ijipti, àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Amoni àwọn ará Moabu, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú aṣálẹ̀; tí wọn ń fá apá kan irun orí wọn; nítorí pé bí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò ṣe kọlà abẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli kò kọlà ọkàn.”