1 Lẹ́yìn náà, mo wo orí àwọn Kerubu, mo rí kinní kan róbótó róbótó, wọ́n dàbí òkúta safire, ìrísí wọn dàbí ìtẹ́.
2 Ọlọrun bá sọ fún ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà pé, “Bọ́ sí ààrin àwọn àgbá tí wọn ń yí, tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn Kerubu. Bu ẹ̀yinná tí ó wà láàrin wọn kún ọwọ́ rẹ, kí o sì fọ́n ọn sórí ìlú yìí káàkiri.” Mo bá rí i tí ó wọlé lọ.
3 Ìhà gúsù ilé náà ni àwọn Kerubu dúró sí nígbà tí ọkunrin náà wọlé, ìkùukùu sì bo àgbàlá ààrin ilé náà.
4 Ìfarahàn ògo OLUWA gbéra kúrò lórí àwọn Kerubu, ó lọ dúró sí àbáwọlé. Ìkùukùu kún gbogbo inú ilé náà, ìmọ́lẹ̀ ògo OLUWA sì kún gbogbo inú àgbàlá.
5 Ariwo ìyẹ́ àwọn Kerubu náà dé àgbàlá òde. Ó dàbí ìgbà tí Ọlọrun Olodumare bá ń sọ̀rọ̀.