15 “Ṣugbọn o gbójú lé ẹwà rẹ; o di alágbèrè ẹ̀sìn nítorí òkìkí rẹ, o sì ń bá gbogbo àwọn eniyan tí wọn ń kọjá ṣe àgbèrè.
16 O mú ninu àwọn aṣọ rẹ, o fi ṣe ojúbọ aláràbarà, o sì ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn níbẹ̀. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.
17 O mú ninu àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati ti fadaka rẹ, tí mo fún ọ, o fi wọ́n ṣe ère ọkunrin, o sì ń bá wọn ṣe àgbèrè.
18 O mú aṣọ rẹ tí a ṣe ọnà sí lára, o dà á bò wọ́n. O gbé òróró ati turari mi kalẹ̀ níwájú wọn.
19 Bẹ́ẹ̀ náà ni oúnjẹ tí mo fún ọ. Mo fún ọ ní ìyẹ̀fun tí ó kúnná, ati òróró, ati oyin pé kí o máa jẹ, ṣugbọn o fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
20 “O mú àwọn ọmọ rẹ ọkunrin ati àwọn ọmọ rẹ obinrin tí o bí fún mi, o fi wọ́n rú ẹbọ ohun jíjẹ fún àwọn oriṣa. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ kékeré ni o pe ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè ẹ̀sìn rẹ,
21 tí o fi ọ̀bẹ dú àwọn ọmọ mi, o fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí àwọn oriṣa?