28 “O bá àwọn ará Asiria ṣe àgbèrè ẹ̀sìn pẹlu, nítorí pé o kò ní ìtẹ́lọ́rùn sibẹ, lẹ́yìn gbogbo àgbèrè tí o ṣe pẹlu wọn, o kò ní ìtẹ́lọ́rùn.
29 O tún ṣe àgbèrè lọpọlọpọ pẹlu àwọn oníṣòwò ará ilẹ̀ Kalidea, sibẹsibẹ, kò tẹ́ ọ lọ́rùn.”
30 OLUWA Ọlọrun ní ọkàn rẹ ti kún fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ jù! Ó ń wò ọ́ bí o tí ń ṣe gbogbo nǹkan wọnyi bí alágbèrè tí kò nítìjú!
31 O mọ ilé oriṣa sí òpin gbogbo òpópó, o sì ń kọ́ ibi ìrúbọ sí gbogbo gbàgede. Sibẹ o kò ṣe bí àwọn alágbèrè, nítorí pé o kò gba owó.
32 Ìwọ iyawo onípanṣágà tí ò ń kó àwọn ọkunrin ọlọkunrin wọlé dípò ọkọ rẹ.
33 Ọkunrin níí máa ń fún àwọn aṣẹ́wó ní ẹ̀bùn, ṣugbọn ní tìrẹ, ìwọ ni ò ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn. O fi ń tù wọ́n lójú, kí wọ́n lè máa wá bá ọ ṣe àgbèrè láti ibi gbogbo.
34 Àgbèrè tìrẹ yàtọ̀ sí ti àwọn aṣẹ́wó yòókù, kò sí ẹni tí ń wá ọ láti bá ọ ṣe àgbèrè; ìwọ ni ò ń fún ọkunrin ní ẹ̀bùn dípò kí wọ́n fún ọ! Èyí ni àgbèrè tìrẹ fi yàtọ̀ sí ti àwọn ẹlòmíràn.