Jeremaya 15:2-8 BM

2 Bí wọ́n bá bi ọ́ pé níbo ni kí àwọn ó lọ, sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní,‘Àwọn tí wọn yóo kú ikú àjàkálẹ̀ àrùn,kì àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n;àwọn tí wọn yóo kú ikú ogun,kí ogun pa wọ́n.Àwọn tí wọn yóo kú ikú ìyàn,kí ìyàn pa wọ́n;àwọn tí wọn yóo lọ sí ìgbèkùn,kí ogun kó wọn lọ.’

3 Oríṣìí ìparun mẹrin ni n óo jẹ́ kí ó dé bá wọn: idà óo pa wọ́n, ajá óo fà wọ́n ya, àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko óo jẹ wọ́n ní àjẹrun.

4 N óo sọ wọ́n di ohun tí ó bani lẹ́rù fún gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé, nítorí ohun tí Manase, ọmọ Hesekaya, ọba Juda, ṣe ní Jerusalẹmu.”

5 OLUWA ní,“Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ta ni yóo ṣàánú yín?Ta ni yóo dárò yín?Ta ni yóo ya ọ̀dọ̀ yín, láti bèèrè alaafia yín?

6 Ẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀,ẹ sì ń pada lẹ́yìn mi; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Nítorí náà ni mo ṣe na ọwọ́ ibinu mi si yín,tí mo sì pa yín run.Mo ti mú sùúrù, ó ti sú mi.

7 Mo ti fẹ́ wọn bí ẹni fẹ́ ọkà ní ibi ìpakà,ní ẹnubodè ilẹ̀ náà.Mo ti kó ọ̀fọ̀ bá wọn;mo ti pa àwọn eniyan mi run,nítorí wọn kò yipada kúrò ní ọ̀nà wọn.

8 Mo ti mú kí opó pọ̀ láàrin wọn ju iyanrìn inú òkun lọ.Mo mú kí apanirun gbógun ti àwọn ìyá àwọn ọdọmọkunrin ní ọ̀sán gangan.Mo mú kí ìbẹ̀rù ati ìwárìrì já lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.