Jeremaya 16:4-10 BM

4 àìsàn burúkú ni yóo pa wọ́n. Ẹnìkan kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin wọ́n; bí ìgbọ̀nsẹ̀ ni wọn yóo rí lórí ilẹ̀. Ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n run, òkú wọn yóo sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko.

5 “Má wọ ilé tí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀, má lọ máa kọrin arò, tabi kí o bá wọn kẹ́dùn, nítorí mo ti mú alaafia mi ati ìfẹ́ mi ati àánú mi kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi.

6 Àtàwọn eniyan pataki pataki, ati mẹ̀kúnnù, ni yóo kú ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní rí ẹni sin òkú wọn, kò ní sí ẹni tí yóo sọkún wọn; ẹnìkan kò ní fi abẹ ya ara, tabi kí ẹnìkan fá orí nítorí wọn.

7 Kò ní sí ẹni tí yóo fún ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní oúnjẹ láti tù ú ninu, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò sì ní bu omi fún ẹnìkan mu, nítorí ikú baba tabi ìyá rẹ̀.

8 “O kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí wọ́n ti ń se àsè, má bá wọn jókòó láti jẹ tabi láti mu.

9 Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: ‘Wò ó! N óo fi òpin sí ẹ̀rín ati ìró ayọ̀ ní ibí yìí, n óo sì fi òpin sí ohùn iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé ati ti ọkọ iyawo. Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ níṣojú yín, ní ìgbà ayé yín.’

10 “Bí o bá sọ ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn eniyan náà tán, bí wọn bá bi ọ́ pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi sọ gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú yìí nípa wa? Kí ni a ṣe? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni a ṣẹ OLUWA Ọlọrun wa?’