Jeremaya 20:7-13 BM

7 OLUWA, o tàn mí jẹ, mo sì gba ẹ̀tàn;o ní agbára jù mí lọ, o sì borí mi.Mo di ẹni ẹ̀sín láti àárọ̀ títí di alẹ́,gbogbo eniyan ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.

8 Gbogbo ìgbà tí mo bá ti sọ̀rọ̀, ni mò ń kígbe pé,“Ogun ati ìparun dé!”Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń kéde sọ mí di ẹni yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru.

9 Ṣugbọn nígbàkúùgbà tí mo bá wí pé n kò ní dárúkọ rẹ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀ mọ́,ọ̀rọ̀ rẹ a máa jó mi ninu bí iná,a sì máa ro mí ninu egungun.Mo gbìyànjú títí pé kí n pa á mọ́ra,ṣugbọn kò ṣeéṣe.

10 Nítorí mò ń gbọ́ tí ọpọlọpọ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé,“Ìpayà wà lọ́tùn-ún lósì,ẹ lọ fẹjọ́ rẹ̀ sùn.Ẹ jẹ́ kí á fẹjọ́ rẹ̀ sùn.”Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń wí,tí wọn sì ń retí ìṣubú mi.Wọ́n ń sọ pé,“Bóyá yóo bọ́ sọ́wọ́ ẹlẹ́tàn,ọwọ́ wa yóo sì tẹ̀ ẹ́;a óo sì gbẹ̀san lára rẹ̀.”

11 Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu mi bíi jagunjagun tí ó bani lẹ́rù.Nítorí náà àwọn tí wọn ń lépa mi yóo kọsẹ̀,apá wọn kò ní ká mi.Ojú yóo tì wọ́n lọpọlọpọ nítorí wọn kò ní lè borí mi.Ẹ̀sín tí ẹnikẹ́ni kò ní gbàgbé yóo dé bá wọn títí lae.

12 OLUWA àwọn ọmọ ogun, ìwọ tíí dán olódodo wò,ìwọ tí o mọ ọkàn ati èrò eniyan.Gbẹ̀san lára wọn kí n fojú rí i,nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.

13 Ẹ kọrin sí OLUWA,ẹ yin OLUWA.Nítorí pé ó gba ẹ̀mí aláìní sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣebi.