6 N óo fi àjàkálẹ̀ àrùn ńlá kọlu àwọn ará ìlú yìí, ati eniyan ati ẹranko ni yóo sì kú.
7 Lẹ́yìn náà n óo mú Sedekaya ọba Juda, ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn, ogun, ati ìyàn, bá pa kù ní ìlú yìí, n óo fi wọ́n lé Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́, òun ati àwọn ọ̀tá tí ń wá ọ̀nà láti pa wọ́n. Ọba Babiloni yóo fi idà pa wọ́n, kò ní ṣàánú wọn, kò sì ní dá ẹnikẹ́ni sí.”
8 OLUWA ní, “Sọ fún àwọn eniyan yìí pé èmi OLUWA ni mo la ọ̀nà meji níwájú wọn: ọ̀nà ìyè ati ọ̀nà ikú.
9 Ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn yóo pa ẹni tí ó bá dúró sinu ìlú yìí; ṣugbọn ẹni tí ó bá jáde tí ó sì fa ara rẹ̀ fún àwọn ará Kalidea, tí ó gbé ogun tì yín, yóo yè, yóo dàbí ẹni tó ja àjàbọ́.
10 Nítorí pé mo ti dójú lé ìlú yìí láti ṣe ní ibi, kì í ṣe fún rere. Ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ ọba Babiloni, yóo sì dá iná sun ún, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
11 OLUWA ní kí n sọ fún ìdílé ọba Juda pé òun OLUWA ní,
12 “Ẹ̀yin ará ilé Dafidi!Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ní òwúrọ̀,ẹ máa gba ẹni tí a jà lólè lọ́wọ́ aninilára,kí ibinu èmi OLUWA má baà ru jáde, nítorí iṣẹ́ ibi yín,kí ó sì máa jó bíi iná,láìsí ẹni tí yóo lè pa á.”