1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda, ọmọ Josaya, OLUWA bá èmi Jeremaya sọ̀rọ̀; ó ní:
2 “Ṣe àjàgà kan pẹlu okùn rẹ̀ kí o sì fi bọ ara rẹ lọ́rùn.
3 Àwọn ikọ̀ kan wá sí ọ̀dọ̀ Sedekaya, ọba Juda, ní Jerusalẹmu, láti ọ̀dọ̀ ọba Edomu ati ọba Moabu, ọba àwọn ọmọ Amoni, ọba Tire, ati ọba Sidoni wá, rán wọn pada sí àwọn oluwa wọn,
4 sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n sọ fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní
5 òun ni òun fi agbára ńlá òun dá ayé: ati eniyan ati ẹranko tí wọ́n wà lórí ilẹ̀; ẹni tí ó bá tọ́ lójú òun ni òun óo sì fi wọ́n fún.
6 Ó ní òun ti fún Nebukadinesari, ọba Babiloni iranṣẹ òun, ní gbogbo àwọn ilẹ̀ wọnyi, òun sì ti fún un ni àwọn ẹranko inú igbó kí wọn máa ṣe iranṣẹ rẹ̀.