1 Ní ọdún kan náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda, ní oṣù karun-un ọdún kẹrin, Hananaya wolii ọmọ Aṣuri, tí ó wá láti Gibeoni bá mi sọ̀rọ̀ ní ilé OLUWA lójú àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan pé,
2 “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun ti ṣẹ́ àjàgà ọba Babiloni.
3 Kí ó tó pé ọdún meji, òun óo kó gbogbo ohun èlò tẹmpili òun pada, tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó láti ibí yìí lọ sí Babiloni.
4 Òun óo mú Jehoiakini ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu, ati gbogbo àwọn tí a kó lẹ́rú láti Juda lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí, nítorí òun óo ṣẹ́ àjàgà ọba Babiloni. Ó ní OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”