1 OLUWA ní, “Ṣé bí ọkọ bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀,tí iyawo náà sì kó jáde nílé ọkọ,tí ó lọ fẹ́ ẹlòmíràn,ṣé ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ lè tún lọ gbà á pada?Ṣé ilẹ̀ náà kò ní di ìbàjẹ́?Lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe àgbèrè pẹlu ọpọlọpọ olólùfẹ́;ẹ wá fẹ́ pada sọ́dọ̀ mi?
2 Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo gbogbo òkè yíká,ibo ni ẹ kò tíì ṣe àgbèrè dé?Ẹ̀ ń dúró de olólùfẹ́ lẹ́bàá ọ̀nà,bí àwọn obinrin Arabia ninu aṣálẹ̀.Ẹ ti fi ìṣekúṣe yín ba ilẹ̀ náà jẹ́.
3 Nítorí náà ni òjò kò ṣe rọ̀,tí òjò àkọ́rọ̀ kò rọ̀ ní àkókò tí ó yẹ.Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń gbéjú gbéré bí aṣẹ́wó,ojú kò sì tì yín.
4 Israẹli, o wá ń pè mí nisinsinyii, ò ń sọ pé,‘Ìwọ ni baba mi, ìwọ ni ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.
5 Ṣé o kò ní dáwọ́ ibinu rẹ dúró ni?Tabi títí ayé ni o óo fi máa bínú?’Lóòótọ́ o ti sọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀,ṣugbọn o ti ṣe ìwọ̀n ibi tí o lè ṣe.”