Jeremaya 30:15-21 BM

15 Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún,nítorí ìnira yín tí kò lóògùn?Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ rékọjá ààlàni mo ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan wọnyi dé ba yín.

16 Ṣugbọn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ yín run, ni a óo pada jẹ run.Gbogbo àwọn ọ̀tá yín patapata, ni yóo lọ sí ìgbèkùn.Gbogbo àwọn tí wọ́n fogun kó yín ni ogun yóo kó.N óo fi ẹrù àwọn tí wọn ń jà yín lólè fún àwọn akónilẹ́rù.

17 N óo fun yín ní ìlera,n óo sì wo àwọn ọgbẹ́ yín sàn,èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Nítorí wọ́n ti pè yín ní ‘Ẹni ìtanù,Sioni tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún.’ ”

18 OLUWA ní,“Mo ṣetán láti dá ire ilé Jakọbu pada,n óo fi ojurere wo ibùgbé rẹ̀.A óo tún ìlú náà kọ́ sórí òkítì rẹ̀,a óo sì tún kọ́ ààfin rẹ̀ sí ààyè rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

19 Orin ọpẹ́ yóo máa ti ibẹ̀ jáde wá,a óo sì máa gbọ́ ohùn àwọn tí ń ṣe àríyá pẹlu.N óo bukun wọn, wọn óo di pupọ,n óo sọ wọ́n di ẹni iyì, wọn kò sì ní jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ.

20 Àwọn ọmọ wọn yóo rí bí wọn ti rí ní àtijọ́,àwọn ìjọ wọn yóo fi ìdí múlẹ̀ níwájú mi.N óo sì fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn ń ni wọ́n lára.

21 Ọ̀kan ninu wọn ni yóo jọba lórí wọn,ààrin wọn ni a óo sì ti yan olórí wọn;n óo fà á mọ́ra, yóo sì súnmọ́ mi,nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè fúnra rẹ̀ súnmọ́ mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.