18 Ṣugbọn bí o kò bá fi ara rẹ le àwọn ìjòyè ọba Babiloni lọ́wọ́, ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Kalidea, wọn yóo sì dáná sun ún, ìwọ pàápàá kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ wọn.”
19 Sedekaya ọba bá wí fún Jeremaya pé, “Ẹ̀rù àwọn ará Juda tí wọ́n sá lọ bá àwọn ará Kalidea ń bà mí. Wọ́n lè fà mí lé wọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì fi mí ṣẹ̀sín.”
20 Jeremaya dáhùn pé, “Wọn kò ní fà ọ́ lé wọn lọ́wọ́. Tẹ̀lé ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń sọ fún ọ; yóo dára fún ọ, a óo sì dá ẹ̀mí rẹ sí.
21 Ṣugbọn bí o bá kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ ohun tí OLUWA fihàn mí nìyí:
22 Wò ó, mo rí i tí wọn ń kó àwọn obinrin tí wọ́n wà ní ààfin ọba Juda jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọ́n sì ń wí pé,‘Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí o fọkàn tán tàn ọ́,wọ́n sì ti ṣẹgun rẹ;nisinsinyii tí o rì sinu ẹrẹ̀,wọ́n pada lẹ́yìn rẹ.’
23 “Gbogbo àwọn aya rẹ ati àwọn ọmọ rẹ ni wọn yóo kó lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kalidea, ìwọ gan-an kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ọwọ́ ọba Babiloni yóo tẹ̀ ọ́, wọn yóo sì dáná sun ìlú yìí.”
24 Sedekaya ọba bá kìlọ̀ fún Jeremaya pé, “Má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ gbogbo nǹkan tí a jọ sọ, o kò sì ní kú.