3 Nítorí pé OLUWA sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, “Ẹ tún oko yín tí ẹ ti patì tẹ́lẹ̀ kọ, ẹ má sì gbin èso sáàrin ẹ̀gún.
4 Ẹ kọ ara yín ní ilà abẹ́ fún OLUWA, kí ẹ sì kọ ara yín ní ilà ọkàn, ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu; kí ibinu mi má baà dé, bí iná tí ó ń jó tí kò sí ẹni tí ó lè pa á, nítorí iṣẹ́ ibi yín.”
5 Ẹ sọ ọ́ ní Juda,ẹ sì kéde rẹ̀ láàrin Jerusalẹmu pé,“Ẹ fọn fèrè káàkiri ilẹ̀ náà,kí ẹ sì kígbe sókè pé,‘Ẹ kó ara yín jọ kí á lọ sí àwọn ìlú olódi.’
6 Ẹ gbé àsíá sókè sí Sioni,pé kí wọn sá àsálà, kí wọn má ṣe dúró,nítorí mò ń mú ibi ati ìparun ńlá bọ̀ láti ìhà àríwá.
7 Kinniun kan ti jáde lọ láti inú igbó tí ó wà;ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n máa ń run àwọn orílẹ̀-èdè ti gbéra;ó ti jáde kúrò ní ipò rẹ̀,láti sọ ilẹ̀ yín di ahoro.Yóo pa àwọn ìlú yín run,kò sì ní sí eniyan ninu wọn mọ́.
8 Nítorí èyí, ẹ fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora,ẹ sọkún kí ẹ máa ké tẹ̀dùntẹ̀dùn,nítorí ìrúnú gbígbóná OLUWAkò tíì yipada kúrò lọ́dọ̀ wa.”
9 OLUWA ní, “Tó bá di ìgbà náà, ojora yóo mú ọba ati àwọn ìjòyè, àwọn alufaa yóo dààmú, ẹnu yóo ya àwọn wolii.”