2 ògo Moabu ti dópin!Wọ́n ń pète ibi sí i ní Heṣiboni,wọ́n ní, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ pa á run, kí ó má jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́!’Ẹ̀yin ará Madimeni pàápàá, kẹ́kẹ́ yóo pa mọ yín lẹ́nu;ogun yóo máa le yín kiri.
3 Gbọ́ igbe kan ní Horonaimu,igbe ìsọdahoro ati ìparun ńlá!
4 “Moabu ti parun; a gbọ́ igbe àwọn ọmọ rẹ̀.
5 Bí wọn tí ń gun òkè Luhiti, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọkún,nítorí pé nígbà tí wọn tí ń lọ níbi ẹsẹ̀ òkè Horonaimu,ni wọ́n tí ń gbọ́ igbe ìparun; pé,
6 ‘Ẹ sá! Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín!Ẹ sáré bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aṣálẹ̀!’
7 “Ọwọ́ yóo tẹ ìwọ náà, Moabu, nítorí pé o gbójú lé ibi ààbò ati ọrọ̀ rẹ.Oriṣa Kemoṣi yóo lọ sí ìgbèkùn, pẹlu àwọn babalóòṣà ati àwọn ìjòyè rẹ̀.
8 Apanirun yóo wọ gbogbo ìlú,ìlú kankan kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀;àwọn àfonífojì yóo pòórá, a óo sì pa àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.