10 OLUWA ti dá wa láre;ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ ròyìn iṣẹ́ OLUWA Ọlọrun wa ní Sioni.
11 Ẹ pọ́n ọfà yín!Ẹ gbé asà yín!Nítorí OLUWA ti ru ẹ̀mí àwọn ọba Media sókè,nítorí pé ó ti pinnu láti pa Babiloni run.Ẹ̀san OLUWA ni, ẹ̀san nítorí tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó.
12 Ẹ gbé àsíá kan sókè, ẹ gbé e ti odi Babiloni;ẹ ṣe ìsénà tí ó lágbára.Ẹ fi àwọn aṣọ́nà sí ipò wọn;ẹ dira fún àwọn kan, kí wọn sápamọ́,nítorí OLUWA ti pinnu, ó sì ti ṣe ohun tí ó sọ nípa àwọn ará Babiloni.
13 Ìwọ Babiloni, tí odò yí ká,tí ìṣúra rẹ pọ̀ lọpọlọpọ,òpin ti dé bá ọ,okùn tí ó so ayé rẹ rọ̀ ti já.
14 OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra,pé òun yóo mú kí àwọn eniyan kún inú rẹ bí eṣú,wọn yóo sì kígbe ìṣẹ́gun lé ọ lórí.
15 OLUWA ni ó fi agbára rẹ̀ dá ilé ayé,tí ó fi ìdí ayé múlẹ̀ pẹlu ìmọ̀ rẹ̀,ó sì fi òye rẹ̀ ta àwọn ọ̀run bí aṣọ.
16 Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀,ojú ọ̀run yóo kún fún alagbalúgbú omi,ó sì ń mú ìkùukùu gòkè láti òpin ilẹ̀ ayé.Ó dá mànàmáná fún òjò,ó sì mú ìjì jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.