Jeremaya 51:25-31 BM

25 Wò ó! Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè ìparun,tí ò ń pa gbogbo ayé run.N óo gbá ọ mú, n óo tì ọ́ lulẹ̀ láti orí àpáta,n óo sì sọ ọ́ di òkè tí ó jóná.

26 Wọn kò ní rí òkúta kan mú jáde ninu rẹ,tí eniyan lè fi ṣe òkúta igun ilé;tabi tí wọn lè fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé,ń ṣe ni o óo wó lulẹ̀ títí ayé.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

27 “Ẹ ta àsíá sórí ilẹ̀ ayé,ẹ fun fèrè ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í,ẹ sì pe àwọn ìjọba jọ láti dojú kọ ọ́;àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè bíi Ararati, Minni, ati Aṣikenasi.Ẹ yan balogun tí yóo gbógun tì í;ẹ kó ẹṣin wá, kí wọn pọ̀ bí eṣú.

28 Kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í,kí àwọn ọba ilẹ̀ Media múra, pẹlu àwọn gomina wọn,ati àwọn ẹmẹ̀wà wọn,ati gbogbo ilẹ̀ tí ó wà lábẹ́ wọn.

29 Jìnnìjìnnì bo gbogbo ilẹ̀ náà,wọ́n wà ninu ìrora,nítorí pé OLUWA kò yí ìpinnu rẹ̀ lórí Babiloni pada,láti sọ ilẹ̀ náà di ahoro,láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀ mọ́.

30 Àwọn ọmọ ogun Babiloni ti ṣíwọ́ ogun jíjà,wọ́n wà ní ibi ààbò wọn;àárẹ̀ ti mú wọn, wọ́n sì ti di obinrin.Àwọn ilé inú rẹ̀ ti ń jóná,àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ sì ti ṣẹ́.

31 Àwọn tí ń sáré ń pàdé ara wọn lọ́nà,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ikọ̀ ń pàdé ara wọn,bí wọ́n ti ń sáré lọ sọ fún ọba Babiloni pé ogun ti gba ìlú rẹ̀ patapata.