59 Jeremaya wolii pa àṣẹ kan fún Seraaya, alabojuto ibùdó ogun, ọmọ Neraya, ọmọ Mahiseaya nígbà tí ó ń bá Sedekaya ọba Juda lọ sí Babiloni ní ọdún kẹrin ìjọba Sedekaya.
60 Jeremaya kọ gbogbo nǹkan burúkú tí yóo ṣẹlẹ̀ sí Babiloni ati gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ nípa rẹ̀ sinu ìwé kan.
61 Ó bá pàṣẹ fún Seraaya pé nígbà tí ó bá dé Babiloni, kí ó rí i dájú pé ó ka gbogbo ohun tí òun kọ sinu ìwé náà sókè.
62 Kí ó sọ pé, “OLUWA, o ti sọ pé o óo pa ibí yìí run, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí nǹkankan tí yóo máa gbé inú rẹ̀ mọ́, ìbáà ṣe eniyan tabi ẹranko. O ní títí lae ni yóo di ahoro.”
63 Jeremaya ní nígbà tí Seraaya bá ka ìwé yìí tán, kí ó di òkúta kan mọ́ ọn kí ó jù ú sí ààrin odò Yufurate,
64 kí ó sì sọ wí pé, “Báyìí ni yóo rí fún Babiloni, kò sì ní gbérí mọ́, nítorí ibi tí OLUWA yóo mú kí ó dé bá a.”Ibí yìí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremaya sọ parí sí.