1 “Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo kó egungun àwọn ọba Juda jáde kúrò ninu ibojì wọn, ati egungun àwọn ìjòyè ibẹ̀; ati ti àwọn alufaa, ati ti àwọn wolii, ati ti àwọn ará Jerusalẹmu.
2 Wọn óo fọ́n wọn dà sílẹ̀ ninu oòrùn, ati lábẹ́ òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n ní ìfẹ́ sí, tí wọ́n sì sìn; àwọn ohun tí wọn ń wá kiri, tí wọn ń ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń bọ. A kò ní kó egungun wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní sin wọ́n. Wọn óo dàbí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí ilẹ̀.
3 Yóo sàn kí àwọn tí ó bá kù ninu ìran burúkú yìí kú ju kí wọ́n wà láàyè lọ, ní ibikíbi tí mo bá lé wọn lọ. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
4 OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé,“Ṣé bí eniyan bá ṣubúkì í tún dìde mọ́?Àbí bí eniyan bá ṣìnà,kì í pada mọ́?
5 Kí ló dé tí àwọn eniyan wọnyi fi yipadakúrò lọ́dọ̀ mi,tí wọn ń lọ láì bojúwẹ̀yìn?Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ni wọ́n sì wawọ́ mọ́;wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi.
6 Mo tẹ́tí sílẹ̀ kí n gbọ́ tiwọn,ṣugbọn wọn kò sọ̀rọ̀ rere.Kò sí ẹni tí ó kẹ́dùn iṣẹ́ ibi rẹ̀,kí ó wí pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’Olukuluku tẹ̀ sí ọ̀nà tí ó wù ú,bí ẹṣin tí ń sáré lọ ojú ogun.