14 ṣugbọn wọ́n ń fi agídí ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, bí àwọn baba wọn ti kọ́ wọn.
15 Nítorí náà, n óo fún wọn ní igi tí ó korò jẹ, n óo sì fún wọn ní omi tí ó ní májèlé mu. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
16 N óo fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ati àwọn baba ńlá wọn kò mọ̀, n óo sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ idà tẹ̀lé wọn títí tí n óo fi pa wọ́n run.”
17 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:“Ẹ ronú sí ọ̀rọ̀ yìí kí ẹ pe àwọn obinrin tíí máa ń ṣọ̀fọ̀ wá,ẹ ranṣẹ pe àwọn obinrin tí wọ́n mọ ẹkún sun dáradára;
18 kí wọ́n wá kíá,kí wọ́n wá máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lé wa lórí,kí omi sì máa dà lójú wa pòròpòrò.
19 Nítorí a gbọ́ tí ẹkún sọ ní Sioni,wọ́n ń ké pé, ‘A gbé!Ìtìjú ńlá dé bá wa,a níláti kó jáde nílé,nítorí pé àwọn ọ̀tá ti wó ilé wa.’ ”
20 Mo ní, “Ẹ̀yin obinrin, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín obinrin ní ẹkún sísun,kí ẹ sì kọ́ aládùúgbò yín ní orin arò.