2 Ìbá ṣe pé mo ní ilé èrò kan ninu aṣálẹ̀,ǹ bá kó àwọn eniyan mi dà sílẹ̀ níbẹ̀,ǹ bá sì kúrò lọ́dọ̀ wọn;nítorí alágbèrè ni gbogbo wọn,ati àgbájọ àwọn alárèékérekè eniyan.
3 Bí ẹni kẹ́ ọrun ni wọ́n kẹ́ ahọ́n wọn,láti máa fọ́n irọ́ jáde bí ẹni ta ọfà;dípò òtítọ́ irọ́ ní ń gbilẹ̀ ní ilẹ̀ náà.OLUWA ní,“Wọ́n ń tinú ibi bọ́ sinu ibi,wọn kò sì mọ̀ èmi OLUWA.”
4 Kí olukuluku ṣọ́ra lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,kí ó má sì gbẹ́kẹ̀lé arakunrin rẹ̀ kankan.Nítorí pé ajinnilẹ́sẹ̀ ni gbogbo arakunrin,a-fọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ sì ni gbogbo aládùúgbò.
5 Olukuluku ń tan ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ,kò sì sí ẹnìkan tí ń sọ òtítọ́.Wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn ní irọ́ pípa;wọ́n dẹ́ṣẹ̀ títí, ó sú wọn,wọn kò sì ronú àtipàwàdà.
6 Ìninilára ń gorí ìninilára,ẹ̀tàn ń gorí ẹ̀tàn,OLUWA ní, “Wọ́n kọ̀ wọn kò mọ̀ mí.”
7 Nítorí náà, ó ní:“Wò ó! N óo fọ̀ wọ́n mọ́,n óo dán wọn wò.Àbí, kí ni kí n tún ṣe fún àwọn eniyan yìí?
8 Ahọ́n wọn dàbí ọfà apanirun,wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.Olukuluku ń sọ̀rọ̀ alaafia jáde lẹ́nu fún aládùúgbò rẹ̀,ṣugbọn ète ikú ni ó ń pa sí i ninu ọkàn rẹ̀.