Jeremáyà 17 BMY

1 “Ẹ̀ṣẹ̀ Júdà ni a fi ṣóóṣó irin kọ sílẹ̀èyí tí ó hàn ketekete pẹ̀lú ẹnu ṣóróṣórósí oókan àyà wọn, àti lórí àwọn ìwotó wà lórí pẹpẹ wọn.

2 Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹàti òpó Áṣérà lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹàti àwọn òkè gíga.

3 Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹpẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ópọ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè yín.

4 Láti ipaṣẹ̀ àìṣedéédé yín ni ẹ̀yinyóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù.Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yínbí ẹrú ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀; nítoríẹ̀yin ti mú inú bí mi, èyí tí yóò sì wà títí ayé.”

5 Báyìí ni Olúwa wí:“Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran ara,àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa

6 Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,kò ní rí ire, nígbà tí ó bá dé yóòmáa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ ihà,ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.

7 “Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrinnáà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.

8 Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadòtí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odòkò sí ìbẹ̀rù fún-un nígbà ooru,gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutùkò sí ìjáyà fún-un ní ọdún ọ̀dábẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

9 Ọkàn kún fún ẹ̀tàn ju ohungbogbo lọ, ó kọjá ohun tí a lèwòsàn, tani èyí lè yé?

10 “Èmi Olúwa ń wo ọkàn àti èròinú ọmọ ènìyàn láti ṣan èrèiṣẹ́ rẹ̀ fún-un, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”

11 Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé niọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ niọ̀nà àìsòdodo. Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ní agbede-méjì ayé rẹ̀, àti níòpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè.

12 Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ní ibi ilé mímọ́ wa.

13 Olúwa olùgbẹ́kẹ̀lé Ísírẹ́lìgbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ niojú ó tì: gbogbo àwọn tí ó padàṣẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ ni a ọ́ kọorúkọ wọn sínú ekuru, nítorí wọ́nti kọ Olúwa orísun omi ìyè wọn sílẹ̀.

14 Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò diẹni ìwòsàn, gbà mí là, èmi yóòdi ẹni ìgbàlà, nítorí ìwọ ni ìyìn mi.

15 Wọ́n sọ fún mi wí pé:“Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà?Jẹ́ kí ó di ìmúsẹ báyìí.”Ni Olúwa wí.

16 Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùsọàgùntàn rẹ, ìwọ mọ̀ wí pé èmikò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú. Ohun tíó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.

17 Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi, ìwọ niààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú

18 Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi,ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínúìtìjú, jẹ́ kí wọn ó bẹ̀rù. Múọjọ́ ibi wá sórí wọn, fi ìparunìlọ́po méjì pa wọ́n run.

Pípa Ọjọ́ Ìsinmí Mọ́

19 Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn Ọba Júdà ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu bodè Jérúsálẹ́mù.

20 Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin Ọba Júdà àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Júdà àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù tí ń wọlé láti ẹnu-bodè yìí.

21 Báyìí ni Olúwa wí ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu-bodè Jérúsálẹ́mù.

22 Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe isẹ́kísẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.

23 Ṣíbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ Ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí.

24 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsí láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ti ẹnu bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kísẹ́ ní ọjọ́ náà.

25 Nígbà náà ni Ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì yóò gba ti ẹnu-bodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹsin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Júdà àti àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé.

26 Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Júdà àti ní agbègbè Jérúsálẹ́mù, láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì àti níbi òkè gúṣù láti orílẹ̀ èdè gíga. Wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti orẹ ọkà ẹran, ọrẹ ọpẹ́ tùràrí àti ìyìn wá sí ilé Olúwa.

27 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ti ẹnu-bodè Jérúsálẹ́mù wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu bodè Jérúsálẹ́mù tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”