1 Nípa ti Ámónì:Ohun tí Olúwa sọ nìyìí:“Ísírẹ́lì kò ha ní ọmọkùnrin?Ṣé kò ha ní àrólé bí?Kí ló wá dé tí Mákómù fi jogún Gádì?Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀?
2 Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀,”ni Olúwa wí;“nígbà tí èmi yóò mú ìdágìrì ogun bá Rábàtí Ámónì yóò sì di òkítì ahoro,gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná.Nígbà náà ni Ísírẹ́lì yóòlé wọn, àwọn tí ó ti lé e jáde,”ni Olúwa wí.
3 “Pohùnréré ẹkún ìwọ Hésíbónìnítorí Áì tí rún, kígbe jádeẹ̀yin ènìyàn Rábà, ẹ wọ aṣọọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀. Ẹ sárésókè sódò nínú ọgbà nítoríMákómù yóò lọ sí ìgbèkùnpẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀.
4 Kí ló dé tí ẹ fi ń fi àfonífojì yín yangàn?Ẹ fi àfonífojì yín yangàn pẹ̀lú èṣo rere,ẹ̀yin ọmọbìnrin aláìsòótọ́.Gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé,‘ta ni yóò kò mí lójú?’
5 Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹláti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,”ni Olúwa wí:
6 “Olúwa àwọn ọmọ ogun.Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì sí ẹnìkantí yóò dá ìkólọ Ámónì padà,”ni Olúwa wí.
7 Nípa Édómù:Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun wí:“Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temánì?Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè?Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?
8 Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò,ìwọ tí ó ń gbé níDédánì nítorí èmi yóò múibi wá sórí Ísọ̀ ní àkókò tí èmi ó fìyà jẹ́ẹ́.
9 Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá;ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀?Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò níkó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́?
10 Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Ísọ̀ sí ìhòòhòèmi kò ní bo ibi ìkọ̀kọ rẹnítorí kí o máa baà fi ara rẹ pamọ́.Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àtiàwọn ará ilé rẹ yóò parun.Wọn kò sì ní sí mọ́.
11 Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀èmi yóò dábòbo ẹ̀mí wọn.Àwọn opó rẹ gan an lè gbékẹ̀lẹ́ mi.”
12 Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ife náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mu un.
13 Èmi fi ara mi búra ni Olúwa wí, wí pé, “Bósírà yóò bayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ẹgún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”
14 Èmi ti gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa:A rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀ èdè láti sọ.Ẹ kó ara yín jọ láti dojúkọ ọ́, ẹ dìde fún ogun.
15 “Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ dikékeré láàrin orílẹ̀ èdè gbogbo;ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn ènìyàn.
16 Ìpayà tí ìwọ ti fà sínúìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ;ìwọ tí ń gbé ní pàlàpáláàpáta tí o jòkó lórí ìtẹ́ gígasíbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì;láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,”ni Olúwa wí.
17 “Édómù yóò di ahorogbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sìfi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ
18 Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sódómùàti Gòmórà pẹ̀lú àwọn ìlútí ó wà ní àyíká rẹ,”ní Olúwa wí.“Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀;kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.
19 “Bí kìnnìún ti ń bọ̀ láti igbóJódánì wá sí pápá oko ọlọ́rà áèmi yóò lé Édómù láti ibi ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá.Ta ni ẹni náà tí èmi yóò yàn fún èyí?Ta lo dàbí èmi, ta ni ó le pè mí níjà?Ta ni olùsọ́ àgùntàn náà tí ó lè dúró níwájú mi?”
20 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí Olúwa ní fún Édómù, ohun tíó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Témánì.Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde.Pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.
21 Nípa ìṣubú ariwo wọn, ilẹ̀yóò mì, a ó gbọ́ igbe wọnní òkun pupa.
22 Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀,yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bóráṣà.Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagunÉdómù yóò dàbí ọkan obìnrin tí ń rọbí.
23 Nípa Dámásíkù:“Inú Hámátì àti Árípádì bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn,wọ́n sì dààmú bí omi òkun.
24 Dámásíkù di aláìlera, ó pẹ̀yindàláti sálọ, ìwárìrì sì dé bá a,ìbẹ̀rù àti ìrora dì í mú, ìrorabí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí.
25 Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀;ìlú tí mo dunnú sí.
26 Lóòtọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹyóò ṣubú lójú pópó, gbogboàwọn ọmọ ogun rẹ yóò paẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,”ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.
27 “Èmi yóò fi iná sí odi Dámásíkù,yóò sì jó gbọ̀ngàn Bẹni-hádádì run.”
28 Nípa Kédárì àti ìjọba Ásọ́rì èyí ti Nebukadinésárì Ọba Bábílónì dojú ìjà kọ:Èyí ni ohun tí Olúwa sọ:“Dìde kí o sì dojú ìjà kọ kédárì,kí o sì pa àwọn ènìyàn ìlà oòrùn run.
29 Àgọ́ wọn àti agbo àgùntàn wọnyóò di gbígbà; ilé wọn yóò diìsínípò padà pẹ̀lú ẹrù àti ràkúnmí wọn.Àwọn ọkùnrin yóò ké pè wọ́n;‘Ìparun ní ibi gbogbo.’
30 “Sálọ kíákíá, dúró nínú ihòìwọ tí ò ń gbé Ásórì,”báyìí ni Olúwa wí.“Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ti dojú ìjà kọ ọ́.
31 “Dìde kí o sì dojú ìjà kọ orílẹ̀ èdèkan pẹ̀lú ìrọ̀rùn, èyítí ó dúró pẹ̀lú ìgboyà;”báyìí ní Olúwa wí.“Orílẹ̀ èdè tí kò ní yálà gbàgede tàbí irin,àwọn ènìyàn re ń dágbé.
32 Àwọn ràkunmí á di ẹrùàti àwọn agbo àgùntàn, wọ́n á di ìkógun.Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́.Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,”báyìí ní Olúwa wí.
33 “Ásọ́rì yóò di ibi ìdọdẹ àwọnakáta, ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé,kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.”
34 Èyí ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èyí tí ó tọ Jeremáyà wòlíì wá nípa Élámù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekáyà Ọba Júdà:
35 Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára sọ:“Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Élámù,ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára.
36 Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rinàgbáyé lòdì sí Élámù.Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rinàti pé, kò sí orílẹ̀ èdè tí ilẹ̀ àjèjì Élámù kò ní lọ.
37 Èmi yóò kẹ́gàn Élámù lójúàwọn ọ̀tá rẹ̀ àti lọ́dọ̀ àwọntí wọ́n jọ ń gbé.Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn,pàápàá ìbínú gbígbóná mi;”bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.“Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn.
38 Èmi yóò sì pa Ọba wọn run àti olórí wọn,”báyìí ni Olúwa wí.
39 “Ṣíbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọẸ́lámù padà láìpẹ́ ọjọ́,”báyìí ni Olúwa wí.