Jeremáyà 21 BMY

Ọlọ́run Kọ Ìbéèrè Sedekáyà Sílẹ̀

1 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremáyà wá nígbà tí Ọba Sedekáyà rán Páṣúrì ọmọ Málíkíjà àti àlùfáà Sedekáyà ọmọ Mánásè síi; wọ́n wí pé:

2 “Wádìí lọ́wọ́ Olúwa fún wa nítorí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ń kọlù wá. Bóyá Olúwa yóò ṣe ìyanu fún wa gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.”

3 Ṣùgbọ́n Jeremáyà dáhùn wí pé, “Sọ fún Sedekáyà,

4 ‘Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá Ọba àti àwọn ará Bábílónì tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí.

5 Èmi gan an yóò sì bá yín jà pẹ̀lú ohun ìjà olóró nínú ìbínú àti ìrunú líle.

6 Èmi yóò sì lu gbogbo ìlú yìí, ènìyàn àti ẹranko, gbogbo wọn ni àjàkálẹ̀-àrùn yóò kọlù tí wọn yóò sì kú.

7 Olúwa sọ pé lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò fi Sedekáyà Ọba Júdà, àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó yọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ogun àti ìyàn lé Ọba Nebukadinésárì àti Bábílónì àti gbogbo ọ̀ta wọn tí ń lépa ẹ̀mí wọn lọ́wọ́. Òun yóò sì fi idà pa wọ́n, kì yóò sì ṣàánú wọn.’

8 “Síwájú síi, sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ: Wò ó, Èmi ń fi ọ̀nà ìyè àti ikú hàn yín.

9 Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró sí ìlú yìí yóò ti ipa idà, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-àrùn kú. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jáde tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn Bábílónì tí ó ń lépa yín yóò sì yè. Òun yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀.

10 Mo ti pinnu láti jẹ ìlú yìí níyà, ni Olúwa wí. A ó sì gbé e fún Ọba Bábílónì, yóò sì run ún pẹ̀lú iná.’

11 “Ẹ̀wẹ̀, wí fún ìdílé Ọba Júdà pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.

12 Ilé Dáfídì èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ:“ ‘Ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ ní àràárọ̀;yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ó ń ni í láraẹni tí a ti jà lólèbí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìbínú mi yóò jáde síta, yóò sì jó bí iná.Nítorí ibi tí a ti ṣe yóò sì jóláìsí ẹni tí yóò pa á.

13 Mo kẹ̀yìn sí ọ, Jérúsálẹ́mùìwọ tí o gbé lórí àfonífojìlórí olókúta tí ó tẹ́jú,Ìwọ tí o ti wí pé, “Ta ni ó le dojú kọ wá?”

14 Èmi yóò jẹ ẹ́ níyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ni Olúwa wí.Èmi yóò mú kí iná jó ilé rẹ̀;ìyẹn yóò jó gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká rẹ.’ ”