1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tó tọ wòlíì Jeremáyà wá nípa àwọn Fílístínì, kí ó tó di pé Fáráò dojúkọ Gásà:
2 Báyìí ni Olúwa wí:“Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá,wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀.Wọn ò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀,ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn.Àwọn ènìyàn yóò kígbe;gbogbo ẹni tó ń gbé lórí ilẹ̀ yóò pohùnréré ẹkún
3 Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró títẹlẹ̀ pátakò ẹsẹ̀ ẹṣin alágbáranígbà tí wọ́n bá gbọ́ ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀tá ńláàti iye kẹ̀kẹ́ wọn.Àwọn baba kò ní lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́;ọwọ́ wọn yóò kákò.
4 Nítorí tí ọjọ́ náà ti péláti pa àwọn Fílístínì run,kí a sì mú àwọn tí ó làtí ó lè ran Tírè àti Sídónì lọ́wọ́ kúrò. Olúwa ti ṣetán láti pa Fílístínì run,àwọn tí ó kù ní agbègbè Káfútò.
5 Gásà yóò fá irun orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀.A ó pa Áṣíkélónì lẹ́nu mọ́;ìyókù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀,ìwọ yóò ti ṣá ara rẹ lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?
6 “Ẹ̀yin kígbe, ‘Yé è, idà Olúwa,yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò sinmi?Padà sínú àkọ̀ re;sinmi kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.’
7 Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe sinmi,nígbà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un,nígbà tí ó ti pa á láṣẹláti dojúkọ Áṣíkélónì àti agbégbé rẹ̀.”