Jeremáyà 11 BMY

1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremáyà wá: láti ọ̀dọ̀ Olúwa:

2 “Fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí o sì sọ wọ́n fún àwọn ènìyàn Júdà, àti gbogbo àwọn tó ń gbé ni Jérúsálẹ́mù.

3 Sọ fún wọn wí pé èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Ègbé ni fún ẹni náà tí kò pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́.

4 Àwọn májẹ̀mú tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, nígbà tí mo mú wọn jáde láti Éjíbítì, láti ìléru ìyọ́rin wá.’ Mo wí pé, ‘Ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo pa láṣẹ fún un yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ènìyàn mi: Èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run yín

5 Nígbà náà ni Èmi ó sì mú ìlérí tí mo búra fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ; láti fún wọn ní ilẹ̀ tí ó ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin,’ ilẹ̀ tí ẹ ní lónìí.”Mo sì dáhùn wí pé, “Àmí, Olúwa.”

6 Olúwa wí fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Júdà àti ní ìgboro Jérúsálẹ́mù pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ìlérí yìí, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn.

7 Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn baba yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá títí di òní, mo kìlọ̀ fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi.”

8 Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ bi ara sí i dípò èyí wọ́n tẹ̀ṣíwájú ni agídí ọkàn wọn. Mo sì mú gbogbo ègún inú májẹ̀mú tí mo ti ṣèlérí, tí mo sì ti pàṣẹ fún wọn láti tẹ̀lé, tí wọn kò tẹ̀lé.’ ”

9 Olúwa sì wí fún mi pé, “Ọ̀tẹ̀ kan wà láàrin àwọn ará Júdà àti àwọn tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.

10 Wọ́n ti padà sí ìdí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn tí ó kọ̀ láti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n ti tẹ̀lé àwọn Ọlọ́run mìíràn láti sìn wọ́n. Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ti fọ́ májẹ̀mú tí mo ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn.

11 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi yóò mu ibi tí wọn kò ní le è yẹ̀ wá sorí wọn, bí wọ́n tilẹ̀ ké pè mí èmi kì yóò fetí sí igbe wọn.

12 Àwọn ìlú Júdà àti àwọn ará Jérúsálẹ́mù yóò lọ kégbe sí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń sun tùràrí sí; àwọn òrìṣà náà kò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìgbà tí ìpọ́nju òhún bá dé.

13 Bí iye àwọn ìlú yín ṣe pọ̀ tó náà ni àwọn òrìṣà yín. Ìwọ Júdà: àwọn pẹpẹ tí o ti pèsè fún jíjó tùràrí sí àwọn Báálì, òrìṣà yẹ̀yẹ́ sì pọ̀ bí iye òpópó tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù.’

14 “Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé Èmi kò ní dẹtí sí wọn ní ìgbà ìpọ́njú.

15 “Kí ni àyànfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹ́ḿpìlì mi,bí ó ṣe ń hu oríṣiríṣi ìwà àrékérekè?Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀?Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ ibi rẹ̀,inú rẹ̀ yóò máa dùn.”

16 Olúwa pè ọ́ ní igi ólífìpẹ̀lú èṣo rẹ tí ó dára ní ojú.Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líleọ̀wọ́ iná ni yóò sun úntí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì dá.

17 Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Ísírẹ́lì àti Júdà ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí fún Báálì.

Ọ̀tẹ̀ Sí Jérúsálẹ́mù

18 Nítorí Ọlọ́run fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n; nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí.

19 Mo ti dàbí ọ̀dọ́ àgùntàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí a mú lọ fún pípa; N kò mọ̀ pé wọ́n ti gbìmọ̀ búburú sí mi wí pé:“Jẹ́ kí a run igi àti èso rẹ̀;jẹ́ kí a gé e kúrò ní orí ilẹ̀ alààyè,kí a mọ́ lè rántí orúkọ rẹ̀ mọ́.”

20 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa àwọn ọmọ ogun,tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo,tí ó ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀mí àti ọkàn,jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn;nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.

21 “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn arákùnrin Ánátótì tí wọ́n ń lépa ẹ̀mí rẹ̀, tí wọ́n ń wí pé, ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìwọ ó kú láti ọwọ́ wa.’

22 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun sọ pé, ‘Èmi yóò fìyà jẹ wọ́n, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn yóò tipasẹ̀ idà kú, ìyàn yóò pa àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

23 Kò ní ṣẹ́ku ohunkóhun sílẹ̀ fún wọn nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí àwọn ènìyàn Ánátótì ní ọdún ìjìyà wọn.’ ”