Jeremáyà 42 BMY

1 Nígbà náà ní gbogbo àwọn ọmọ ogun àti Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti Jésánáyà omọkùnrin Hòsáyà àti kékeré títí dé orí ẹni ńlá wá.

2 Sí ọ̀dọ̀ Jeremáyà wòlíì náà, wọ́n sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún gbogbo ìyókù yìí. Nítorí gẹ́gẹ́ bi ìwọ ṣe rí i nísinsin yìí pé a pọ̀ níye nígbà kan rí; ṣùgbọ́n báyìí àwa díẹ̀ la sẹ́kù

3 Gbàdúrà pé kí Olúwa Ọlọ́run rẹ sọ ibi tí àwa yóò lọ fún wa àti ohun tí àwa yóò ṣe.”

4 Wòlíì Jeremáyà sì dáhùn wí pé, “Mo ti gbọ́. Èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ṣe bèèrè. Èmi yóò sọ gbogbo ohun tí Olúwa bá sọ fún un yín, ń kò sì ní fi ohunkóhun pamọ́ fún un yín.”

5 Nígbà náà ni wọ́n sọ fún Jeremáyà wí pé, “Kí Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ àti òdodo láàrin wa, bí àwa kò bá ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá rán ọ láti sọ fún wa.

6 Ìbá à ṣe rere, ìbá à ṣe búburú, àwa yóò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run wa; èyí tí àwa ń rán ọ sí; Kí ó ba à lè dára fún wa. Nítorí pé àwa yóò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run wa.”

7 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé;

8 Nígbà náà ni a ó pa Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀; àti gbogbo àwọn ènìyàn láti orí ẹní tí ó kéré dé orí ẹni ńlá.

9 Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì wí: ‘Èyí ni ẹni tí ẹ̀yin ti rán láti gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ ṣíwájú mi.

10 Bí ẹ̀yin bá gbé ní ilẹ̀ yìí, èmi yóò gbé e yín ró, n kò sí ní fà yín lulẹ̀, èmi yóò gbìn yín, n kì yóò fà yín tu nítorí wí pé èmi yí ọkan padà ní ti ibi tí mo ti ṣe sí i yín.

11 Ẹ má ṣe bẹ̀rù Ọba Bábílónì tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù, báyìí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ ni Olúwa wí; nítorí tí èmi wà pẹ̀lú yín láti pa yín mọ́ àti láti gbàyín ní ọwọ́ rẹ̀.

12 Èmi yóò fi àánú hàn sí i yín, kí ó lè ṣàánú fún un yín, kí ó sì mú un yín padà sí ilẹ̀ yín.’

13 “Àmọ́ ṣá, bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Àwa kò ní gbé ilẹ̀ yìí,’ ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín.

14 Àti pé bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò lọ gbé ní Éjíbítì; níbi tí àwa kì yóò rí ìró ogunkógun, tí a kì yóò sì gbọ́ ìró fèrè, tí ebi oúnjẹ kì yóò sì pa wá, níbẹ̀ ni àwa ó sì máa gbé,’

15 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ìyókù Júdà èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí: ‘Bí ẹ̀yin bá pinnu láti lọ sí Éjíbítì láti lọ ṣe àtìpó ńibẹ̀.

16 Yóò sì ṣe, idà tí ẹ̀yin bẹ̀rù yóò sì lé e yín bá níbẹ̀; àti ìyànu náà tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù yóò sì tẹ̀lé yín lọ sí Éjíbítì àti pé ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò kú sí.

17 Nítorí náà, gbogbo àwọn tí ó ti pinnu láti ṣe àtìpó ní Éjíbítì ni yóò ti ipa idà kú, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn kò sì ní jẹ́ kí ẹníkẹ́ni nínú wọn yè tàbí sá àsálà nínú ibi tí èmi yóò mú wá sórí wọn.’

18 Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí èmi ti da ìbínú àti ìrunú síta sórí àwọn tí ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ ni ìrunú mi yóò dà sita sórí yín, nígbà tí ẹ̀yin bá lọ sí Éjíbítì. Ẹ̀yin ó sì di ẹni ègún àti ẹní ẹ̀gàn àti ẹ̀sín, ẹ̀yin kì yóò sì rí ibí yìí mọ́.’

19 “Ẹ̀yin yóòkù Júdà, Olúwa ti sọ fún un yín pé, ‘Kí ẹ má ṣe lọ sí Éjíbítì.’ Ẹ mọ èyí dájú: Èmi kìlọ̀ fún un yín lónìí;

20 Pé àṣìṣe ńlá gbáà ni ẹ̀yin ṣe nígbà tí ẹ̀yin rán mi sí Olúwa Ọlọ́run yín pé, ‘Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa; sọ fún wa gbogbo ohun tí ó bá sọ, àwa yóò sì ṣe é.’

21 Mo ti sọ fún un yín lónìí, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹ̀yin kò tí ì gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run yín, àti gbogbo ohun tí ó rán mi láti sọ fún un yín.

22 Ǹjẹ́ nísinsìnyìí ẹ mọ èyí dájú pé: Ẹ̀yin yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn níbikíbi tí ẹ̀yin bá fẹ́ lọ láti ṣe àtìpó.”