1 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà wòlíì sọ fún Bárúkì ọmọ Néríà ní ọdún kẹrin ti Jéhóíákímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà. Lẹ́yìn tí Bárúkì ti kọ sínú ìwé kíká àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ti ń sọ:
2 “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ sí Bárúkì:
3 Ó wí pé, ‘Ègbé ni fún mi! Olúwa fi kún ìṣòro tí mo ní; mo di aláàbọ̀-ara pẹ̀lú ìrora àti àìní ìfọ̀kànbalẹ̀.’ ”
4 Olúwa wí pé sọ èyí fún un, “Èyí ni Ọlọ́run sọ: ‘Èmi yóò sí ipò àwọn ohun tí mo ti kọ àti pé: Èmi yóò wú àwọn nǹkan tí mo gbìn sí orí ilẹ̀ náà.
5 Ṣé ìwọ yóò wá ohun rere fún ara rẹ? Nítorí náà, má ṣe wá wọn. Èmi yóò mú ibi wá sí orí àwọn ènìyàn gbogbo ni Olúwa wí. Níbikíbi tí o bá lọ ni èmi yóò jẹ́ kí o sá àsálà ẹ̀mí rẹ ní àlàáfíà.’ ”