Jeremáyà 33 BMY

Ìlérí Ìmúpadàsípò

1 Nígbà tí Jeremáyà wà nínú àgbàlá túbú, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ̀ ọ́ wá lẹ́ẹ̀kejì:

2 “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ẹni tí ó dá ayé, Olúwa tí ó mọ ayé tí ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, Olúwa ni orúkọ rẹ̀:

3 ‘Pè mí, èmi ó sì dá ọ lóhùn, èmi ó sì sọ ohun alágbára ńlá àti ọ̀pọ̀ ohun tí kò ṣe é wádìí tí ìwọ kò mọ̀ fún ọ.’

4 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì sọ nípa àwọn ilẹ̀ ìlú yìí àti ààfin àwọn Ọba Júdà tí ó ti wó lulẹ̀ nítorí àwọn ìdọ̀tí àti idà

5 Nínú ìjà pẹ̀lú Kálídéà: ‘Wọn yóò kún fún ọ̀pọ̀ òkú ọmọkùnrin tí èmi yóò pa nínú ìbínú àti nínú ìrunú mi. Èmi ó pa ojú mi mọ́ kúrò ní ìlú yìí nítorí gbogbo búburú wọn.

6 “ ‘Síbẹ̀, èmi ó mú okun àti ìwòsàn wá; èmi ó wo àwọn ènìyàn mi sàn. Èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó jẹ ìgbádùn ìyè lọ́pọ̀lọpọ̀ àti ìṣọ́.

7 Èmi ó mú Júdà àti Ísírẹ́lì kúrò nínú ìgbékùn, èmi ó sì tún wọn kọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀.

8 Èmi ó wẹ̀ wọ́n nù kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ sími. Èmi ó sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àìṣedédé wọn sí mi jìn wọ́n.

9 Nígbà náà ni ìlú yìí ó fún mi ní òkìkí, ayọ̀, ìyìn àti ọlá níwájú gbogbo orílẹ̀ èdè ayé; tí wọ́n gbọ́ gbogbo rere tí èmi ṣe fún wọn. Wọn ó sì bẹ̀rù, wọn ó wárìrì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore àti àlàáfíà tí èmi pèṣè fún wọn.’

10 “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa ti ilẹ̀ yìí pé ó dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran. Síbẹ̀ ní ìlú Júdà ní pópónà ti Jérúsálẹ́mù tí ó di àkọsílẹ̀ láìsí ẹni tó gbé ibẹ̀; yálà ní ọkùnrin tàbí àwọn ẹran, wọn ó gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí.

11 Ariwo di ayọ̀ àti inú dídùn, ohùn ìyàwó àti ti ọkọ ìyàwó àti ohùn àwọn tí ó ru ẹbọ ọpẹ́ wọn nílé Olúwa wí pé:“Yin Olúwa àwọn ọmọ ogun,nítorí Olúwa dára,ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé.”Nítorí èmi ó dá ìkólọ ilẹ̀ náà padà sí bí o ṣe wà tẹ́lẹ̀ ni Olúwa wí:

12 “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, ‘Ní ilẹ̀ yìí tí ó ti dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran nínú gbogbo ìlú, kò ní sí pápá oko fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn láti mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sinmi.

13 Ní ìlú orílẹ̀ èdè òkè wọn, ní ìhà gúṣù ilẹ̀ olókè ní ilẹ̀ ti Bẹ́ńjámínì ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká àti ní ìlú Júdà ni agbo yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni Olúwa wí.

14 “ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ṣẹ.

15 “ ‘Ní ọjọ́ wọ̀n ọn nì àti ní àkókò náà,Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dáfídì.Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà.

16 Ní ọjọ́ wọ̀n ọn nì, Júdà yóò di ẹni ìgbàlà.Jérúsálẹ́mù yóò sì máa gbé láìséwuOrúkọ yìí ni a ó máa pè é Olúwa wa olódodo.’

17 Nítorí báyìí ni Olúwa wí: ‘Dáfídì kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Ísírẹ́lì.

18 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ ọmọ Léfì kò ní kùnà láti ní ọkùnrin kan tí ó dúró níwájú mi ní gbogbo ìgbà láti rú ẹbọ sísun; ẹbọ jíjẹ àti láti pèsè ìrúbọ.’ ”

19 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremáyà wá wí pé:

20 “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Tí ìwọ bá lè dá májẹ̀mú mi ní òru tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀sán àti òru kò lè sí ní àkókò wọn mọ́.

21 Nígbà náà ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Léfì tí ó jẹ́ àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ níwájú mi lè bàjẹ́, tí Dáfídì kò sì rí ẹni láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.

22 Èmi ó mú àwọn ọmọlẹ́yìn Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti Léfì tí ó jẹ́ oníwàásù níwájú mi di bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí kò ṣe é kà àti bí iyẹ̀pẹ̀ ojú òkun tí kò ṣe é wọ̀n.’ ”

23 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé:

24 “Ǹjẹ́ ìwọ kò kíyèsí pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ pé: ‘Olúwa ti kọ àwọn Ọba méjèèjì tí ó yàn sílẹ̀’? Nítorí náà, ni wọ́n ti ṣe kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi. Wọn kò sì mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè kan.

25 Báyìí ni Olúwa wí: ‘Bí èmi kò bá ti da májẹ̀mú mi pẹ̀lú ọ̀sán àti òru àti pẹ̀lú òfin ọ̀run àti ayé tí kò lè yẹ̀.

26 Nígbà náà ni èmi ó kọ ọmọlẹ́yìn Jákọ́bù àti Dáfídì ìránṣẹ́ mi tí èmi kò sì ní yan ọ̀kan nínú ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ alákóso lórí àwọn ọmọlẹ́yìn Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù; nítorí èmi ó mú ìkólọ wọn padà; èmi ó sì ṣàánú fún wọn.’ ”