1 Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, wí pé:
2 “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, pé: ‘Ìwọ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ sínú ìwé kan.
3 Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni Olúwa Ọlọ́run wí.”
4 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Ísírẹ́lì àti Júdà:
5 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrìláìṣe igbe àlàáfíà.
6 Béèrè kí o sì rí:Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí?Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrintí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí,tí ojú gbogbo wọn sì fàro fún ìrora?
7 Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó!Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀,Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jákọ́bùṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.
8 “ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa wí pé;‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn,Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù.Àwọn alejo kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́
9 Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọnàti Dáfídì gẹ́gẹ́ bí Ọba wọn,ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn.
10 “ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi,má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì,’ni Olúwa wí.‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jínjìn wá,àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn.Jákọ́bù yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà,kò sì sí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.
11 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’ni Olúwa wí.‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀ èdè run,nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká,síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátapáta.Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan;Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’
12 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn,bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn.
13 Kò sí ẹnìkan tí yóò bẹ̀bẹ̀ fún àìṣedéédéé yín,kò sí ètùtù fún ọgbẹ́ yín,a kò sì mú yín láradá.
14 Gbogbo àwọn ìbátan yín ló ti gbàgbé yín,wọn kò sì náání yín mọ́ pẹ̀lú.Mo ti nà yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀ta yín yóò ti nà yínmo sì bá a yín wí gẹ́gẹ́ bí ìkànítorí tí ẹ̀bi yín pọ̀ púpọ̀,ẹ̀ṣẹ̀ yín kò sì lóǹkà.
15 Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín,ìrora yín èyí tí kò ní oògùn?Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó gani mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín.
16 “ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá,àní gbogbo àwọn ọ̀ta yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjòjì;gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.
17 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín,n ó sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ni Olúwa wí,‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiriSíónì tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’
18 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘Èmi yóò dá gbogbo ire àgọ́ Jákọ́bù padà,èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀;ìlú náà yóò sì di títúnṣetí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀.
19 Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àtiìyìn yóò sì ti máa jáde.Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀,wọn kì yóò sì dínkù ní iye,Èmi yóò fi ọlá fún wọn,wọn kò sì ní di ẹni àbùkù.
20 Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanìníwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí.Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára,ni èmi yóò fìyà jẹ.
21 Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn,Ọba wọn yóò dìde láti àárin wọn.Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi,nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jìn láti súnmọ́ mi?
22 Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi,èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín,’ ”ni Olúwa wí.
23 Wò ó, ìbínú Ọlọ́run yóò tú jáde,ìjì líle yóò sì sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn búburú.
24 Ìbínú ńlá Ọlọ́run kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìnàwọn ìkà títí yóò fi múèròǹgbà ọkàn rẹ̀ ṣẹ.Ní àìpẹ́ ọjọ́,òye rẹ̀ yóò yé e yín.