Jeremáyà 48 BMY

Iṣẹ́ Nípa Móábù

1 Nípa Móábù:Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí:“Ègbé ni fún Nébò nítorí a ó parun.A dójú ti Kíríátaímù, a sì mú un,ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká.

2 Móábù kò ní ní ìyìn mọ́,ní Héṣíbónì ni wọn ó pète ìparun rẹ̀,‘Wá, kí a pa orílẹ̀ èdè náà run.’Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́,a ó fi idà lé e yín.

3 Gbọ́ igbe ní Horonáímù,igbe ìrora àti ìparun ńlá.

4 Móábù yóò di wíwó palẹ̀;àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta.

5 Wọ́n gòkè lọ sí Lúhítì,wọ́n ń sunkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ;ní ojú ọ̀nà sí Horonáímùigbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ.

6 Sá! Àsálà fún ẹ̀mí rẹ;kí o dàbí igbó ní aṣálẹ̀.

7 Níwọ̀n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ,a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn,Sémọ́sì náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùnpẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀.

8 Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ,ìlú kan kò sì ní le là.Àfonífojì yóò di ahoroàti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run,nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

9 Fi iyọ̀ sí Móábù,nítorí yóò ṣègbé,àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoroláìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀.

10 “Ìfibú ni fún ẹni tí ó dúró láti ṣe iṣẹ́ Olúwa,ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.

11 “Móábù ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wábí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀,tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejìkò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí.Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ,òórùn rẹ̀ kò yí padà.

12 Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀,”ni Olúwa wí,“nígbà tí n ó rán àwọn tí ó da ọtí láti inú àwọn ìgòtí wọ́n ó sì dà á síta;Wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo,wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀.

13 Nígbà náà Móábù yóò sì tú u nítorí kémósì,bí ojú ti í ti ilé Ísírẹ́lìnígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Bétélì.

14 “Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘ajagun ni wá,alágbára ní ogun jíjà’?

15 A ó pa Móábù run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀;a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,”ni Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

16 “Ìṣubú Móábù súnmọ́;ìpọ́njú yóò dé kánkán.

17 Ẹ dárò fún, gbógbó ẹ̀yin tí ó yí i kágbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó.Ẹ sọ pé, ‘Báwo ni ọ̀pá agbára rẹtítóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́!’

18 “Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ,kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ,ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Díbónì,nítorí tí ẹni tí ó pa Móábù runyóò dojúkọ ọ́yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.

19 Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran,ìwọ tí ń gbé ní Áróà.Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà‘kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’

20 Ojú ti Móábù nítorí tí a wó o lulẹ̀,ẹ hu, sì kígbe síta!Ámónì kéde péa pa Móábù run.

21 Ìdájọ́ ti dé sí Pílátéùsórí Hólónì, Jáhásà àti Mẹ́fátì,

22 sórí Díbónì, Nébò àti Bẹti Díbílátaímù

23 sórí Kíríátaímù, Bẹti Gámù àti Bẹti Méónì,

24 sórí Kéríótì àti Bóásì,sórí gbogbo ìlú Móábù, nítòsí àti ní ọ̀nà jínjìn.

25 A gé ìwo Móábù kúrò,apá rẹ̀ dá,”ni Olúwa wí.

26 “Ẹ jẹ́ kí a mú u mutínítorí ó kó ìdọ̀tí bá Olúwa,jẹ́ kí Móábù pàfọ̀ nínú èébì rẹ̀,kí ó di ẹni ẹ̀gàn.

27 Ǹjẹ́ Ísírẹ́lì kò di ẹni ẹ̀gan rẹ?Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olètó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́nígbákùúgbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

28 Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrin àwọn òkúta,ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Móábù.Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀sí ẹnu ihò.

29 “A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù:àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀.

30 Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni,”ni Olúwa wí,“ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkankan.

31 Nítorí náà, mo pohùnréréẹkún lórí Móábù fún àwọnará Móábù ni mo kígbe lóhùn raraMo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin Kíháráṣè.

32 Mo sunkún fún ọ bí Jásì ṣe sunkúnìwọ àjàrà Síbínà.Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé òkun wọn,Ámónì,ajẹnirun ti kọlu èṣo rẹàti àwọn èṣo àjàrà rẹ.

33 Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrònínú ọgbà àjàrà àti okoMóábù, mo dá ọwọ́ṣíṣàn ọtí wáìnì dúrólọ́dọ̀ olùfúnni; kò sí ẹni tíó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ti ayọ̀.

34 “Ohùn igbe wọn gòkè látiHésíbónì dé Élíà àti Jásìláti Sóà títí dé Hórónáímùàti Éjíbítì Sélíáyà, nítoríàwọn omi Nímírímù pẹ̀lú ti gbẹ

35 Ní ti Móábù ni èmi yóò ti fiòpin sí ẹni tí ó rúbọsí ibí gíga àti ẹni tí ń suntùràrí fún òrìṣà rẹ̀,”ni Olúwa wí.

36 “Nítorí náà ọkàn mi rófún Móábù bí fèrè oróHíhárésétì ìṣúra ńlátí wọ́n kójọ ṣègbé.

37 Gbogbo orí mi ni ó pá,gbogbo irungbọ̀n ni a gé kúrò,gbogbo ọwọ́ ni a ṣá lọ́gbẹ́, àtiaṣọ ọ̀fọ̀ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́.

38 Ní gbogbo orílẹ̀ èdèMóábù àti ní ita kò síohun kan bí kò ṣe ọ̀fọ̀, nítorítí mo fọ́ Móábù bí a ti ń fọ́ohun elò tí kò wu ni,”ni Olúwa wí.

39 “Èéṣe tí ẹ fi fọ́ túútúú,tí ẹ sì fi ń pohùnréré ẹkún!Báwo ni Móábù ṣe yíẹ̀yìn padà ní ìtìjú!Móábù ti di ẹni ìtìjú àti ẹ̀gàn àtiìdààmú sí gbogbo àwọn tí ó yìí ká.”

40 Báyìí ni Olúwa wí:“Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí Móábù.

41 Koríko kan yóò di kíkóàti àwọn ìlú olódì.Ní ọjọ́ náà ọkàn akọni Móábùyóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí.

42 A ó pa Móábù run gẹ́gẹ́ bíorílẹ̀ èdè nítorípé ó gbéraga sí Olúwa.

43 Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídèń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Móábù,”ní Olúwa wí.

44 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fúnẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìnẹnikẹ́ni tí o bá jáde sítanínú ọ̀fìn ní à ó múnínú okùn dídè nítorí tíèmi yóò mú wá sóríMóábù àní ọdún Ìjìyà rẹ,”ní Olúwa wí.

45 “Ní abẹ́ òjìji Hésíbónìàwọn tí ó sá dúró láìníolùrànlọ́wọ́ nítorí iná ti jáde wáláti Hésíbónì àti ọwọ́ ináláti àárin Síónì sì jó iwájú orí Móábù runàti agbárí àwọn ọmọ àlùfáà.

46 Ègbé ní fún ọ Móábù!Wọn yóò sì kó àwọn ọmọkùnrin yín lọ síilẹ̀ àjèjì àti àwọn ọmọbìnrin yín lọ sí ìgbékùn.

47 “Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọMóábù padà ní ọjọ́ ìkẹyìn,”ni Olúwa wí.