1 Ní ọdún kẹrin Jéhóíákímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé:
2 “Mú ìwé kíká fún ará rẹ, kí o sì kọ sínú rẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ nípa Ísírẹ́lì àti ti Júdà, àti sí gbogbo orílẹ̀ èdè láti ìgbà tí mo ti sọ fún ọ láti ọjọ́ Jòsáyà títí di òní.
3 Ó lè jẹ́ wí pé ilé Júdà yóò gbọ́ gbogbo ibi tí mo ti pinnu láti ṣe fún wọn; kí wọn kí ó sì yípadà, olúkúlùkù wọn kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀. Kí èmi kí ó lè dárí àìṣedédé àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n.”
4 Nígbà náà ni Jeremáyà pe Bárúkì ọmọ Neráyà, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run báa sọ fún, Bárúkì sì kọ láti ẹnu Jeremáyà, gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ fún-un sórí ìwé kíká náà.
5 Nígbà náà ni Jeremáyà wí fún Bárúkì pé, “A ṣé mi mọ́! Èmi kò lè lọ sí ilé Olúwa.
6 Nítorí náà, ìwọ lọ sí ilé Olúwa ní ọjọ́ ààwẹ̀, kí o sì kà nínú ìwé kíkà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ ti ẹnu mi kọ; ìwọ ó sì kà á ní etí gbogbo Júdà, tí wọ́n jáde wá láti ìlú wọn.
7 Ó lè jẹ́ pé, ẹbọ wọn yóò wá sí iwájú Olúwa, wọ́n ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn; nítorí pé títóbi ni ìbínú àti ìrunú tí Olúwa ti sọ sí àwọn ènìyàn yìí.”
8 Bárúkì ọmọ Neráyà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí wòlíì Jeremáyà sọ fún, láti ka ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé ní ilé Olúwa.
9 Ní oṣù kẹ́sàn-án ọdún karùn-ún Jéhóíákímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà ni wọ́n kéde ààwẹ̀ níwájú Olúwa fún gbogbo ènìyàn Jérúsálẹ́mù àti fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wá láti Júdà.
10 Láti inú yàrá Gémáríà ọmọ Sáfánì akọ̀wé, ní àgbàlá òkè níbi ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa tuntun. Bárúkì sì ka ọ̀rọ̀ Jeremáyà láti inú ìwé ní ilé Olúwa sí etí gbogbo ènìyàn.
11 Nígbà tí Míkáyà ọmọ Gémáríà ọmọ Sáfánì gbọ́ gbogbo àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé náà;
12 Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé Ọba sínú yàrá akọ̀wé; níbi tí gbogbo àwọn ìjòyè gbé jókòó sí: Élísámà akọ̀wé, Déláyà ọmọ Sámáyà, Elinátanì ọmọ Ákíbórì, Gémáríà ọmọ Sáfánì àti Sedekáyà ọmọ Hananáyà àti gbogbo àwọn ìjòyè.
13 Lẹ́yìn tí Míkáyà sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí o ti gbọ́ fún wọn, nígbà tí Bárúkì kà láti inú ìwé kíkà náà ní etí àwọn ènìyàn.
14 Gbogbo àwọn ìjòyè sì rán Jéhúdù ọmọ Métamáyà ọmọ Sélémáyà ọmọ Kúsì sí Bárúkì wí pé, mú ìwé kíká náà ní ọwọ́ rẹ láti inú èyí tí ìwọ kà ní etí àwọn ènìyàn; kí o si wá. Nígbà náà ni Bárúkì ọmọ Nétayà wá sí ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú ìwé kíká ní ọwọ́ rẹ̀.
15 Wọ́n sì wí fún pé, “Jòkòó, jọ̀wọ́ kà á sí etí wa!”Nígbà náà ni Bárúkì sì kàá ní etí wọn.
16 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà tan; wọ́n ń wo ara wọn lójú pẹ̀lú ẹ̀rù. Wọ́n sì wí fún Bárúkì pé, “Àwa gbọdọ̀ jábọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Ọba.”
17 Wọ́n sì bèèrè lọ́wọ́ Bárúkì pé, “Sọ fún wa báwo ni o ṣe kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Ṣé Jeremáyà ló sọ wọ́n?”
18 Bárúkì sì dá wọn lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, láti ẹnu rẹ̀ ni, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ báyìí fún mi, èmi sì fi tàdáwà kọ wọ́n sínú ìwé náà.”
19 Nígbà náà ni àwọn ìjòyè sọ fún Bárúkì wí pé, “Lọ fi ara rẹ pamọ́ àti Jeremáyà, má sì ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ibi tí ẹ̀yin wà.”
20 Lẹ́yìn tí wọ́n fi ìwé kíkà náà pamọ́ sí iyàrá Elisámà akọ̀wé, wọ́n sì wọlé tọ Ọba lọ nínú àgbàlá, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà ní etí Ọba.
21 Ọba sì rán Jéhúdù láti lọ mú ìwé kíká náà wá láti inú iyàrá Elisámà akọ̀wé. Ó sì ka ìwé náà ní etí Ọba àti ní etí gbogbo àwọn ìjòyè tí ó dúró ti Ọba.
22 Ó sì jẹ́ ìgbà òtútù nínú oṣù kẹsàn-án, Ọba sì jókòó ní ẹ̀bá iná àrò, iná náà sì ń jó ní iwájú rẹ̀.
23 Nígbà tí Jéhúdù ka ojú ìwé mẹ́ta sí mẹ́rin nínú ìwé náà, Ọba fi ọ̀bẹ gé ìwé, ó sì sọ sínú iná tí ó wà nínú ìdáná, títí tí gbogbo ìwé náà fi jóná tán.
24 Síbẹ̀, Ọba àti gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò bẹ̀rù; wọn kò sì fa aṣọ wọn yá.
25 Elinátanì, Déláyà àti Jemaríà sì bẹ Ọba kí ó má ṣe fi ìwé náà jóná, ṣùgbọ́n Ọba kọ̀ láti gbọ́ ti wọn.
26 Dípò èyí Ọba pàṣẹ fún Jeremélì ọmọ Hamelékì, Seráyà ọmọ Ásíráélì àti Selemáyà ọmọ Ábídélì láti mú Bárúkì akọ̀wé àti Jeremáyà wòlíì ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi wọ́n pamọ́.
27 Lẹ́yìn tí Ọba fi ìwé kíkà náà tí ọ̀rọ̀ tí Bárúkì kọ láti ẹnu Jeremáyà jóná tán, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì tọ Jeremáyà wá:
28 “Wí pé, tún mú ìwé kíká mìíràn kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé kíká èkínní tí Jéhóíákímù Ọba Júdà fi jóná.
29 Kí o sì wí fún Jéhóíákímù Ọba Júdà pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ìwọ ti fi ìwé kíká náà jóná, o sì wí pé, “Èése tí ìwọ fi kọ̀wé sínú rẹ̀, pé lòótọ́ ni Ọba Bábílónì yóò wá, yóò sì pa ilẹ̀ run, àti ènìyàn, àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀.”
30 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí níti Jéhóíákímù Ọba Júdà pé: Òun kì yóò ní ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì, à ó sì sọ òkú rẹ̀ nù fún ooru ní ọ̀sán àti fún òtútù ní òru.
31 Èmi ó sì jẹ òun àti irú ọmọ rẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ̀ níyà nítorí àìṣedédé wọn; èmi ó sì mú gbogbo ibi tí èmi ti sọ sí wọn wá sórí wọn, àti sórí àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn Júdà, nítorí tí wọn kò fetísí mi.’ ”
32 Nígbà náà ni Jeremáyà mú ìwé kíká mìíràn fún Bárúkì akọ̀wé ọmọ Neráyà, ẹni tí ó kọ̀wé sínú rẹ̀ láti ẹnu Jeremáyà gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé tí Jéhóíákímù Ọba Júdà ti sun níná. A sì fi onírúurú ọ̀rọ̀ bí irú èyí kún pẹ̀lú.