1 Bákan náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
2 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ìyàwó, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin níbí yìí.”
3 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí wọ́n bá bí nílẹ̀ yìí, àti ìyá tí ó bí wọn àti bàbá wọn.
4 “Wọn yóò kú ikú àrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí sọ̀fọ̀ fún wọn. Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀; wọn ó ṣègbé pẹ̀lú ọ̀kọ̀ àti ìyàn. Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.”
5 Nítorí báyìí ni Olúwa wí: “Má ṣe wọ ilé tí oúnjẹ ìsìnkú wà, má se lọ ibẹ̀ láti káànú tàbí sọ̀fọ̀, nítorí mo ti mú ìbùkún, ìfẹ́ àti àánú mi kúrò lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” ni Olúwa wí.
6 “Àti ẹni ńlá àti kékeré ni yóò ṣègbé ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní sin wọ́n tàbí sọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóò fá irun orí wọn nítorí wọn.
7 Kò sí ẹni tí yóò fi oúnjẹ tu àwọn tí í sọ̀fọ̀ nínú, kódà kì í ṣe fún bàbá tàbí fún ìyá, kì yóò sí ẹni tí yóò fi ohun mímu tù wọ́n nínú.
8 “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí àsà wà, má ṣe jókòó jẹun tàbí mu ohun mímu.
9 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí: Ní ojú yín ní ọjọ́ yín ni òpin yóò débá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú, àti sí ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó ní ibí yìí.
10 “Nígbà tí o bá sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yìí, tí wọ́n bá sì bi ọ́ wí pé, ‘È é ṣe tí Olúwa ṣe mú búburú yìí bá wa? Kí ni àṣìṣe tí àwa ṣe? Kínni ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa?’
11 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ fún wọn wí pé, ‘Nítorí tí àwọn baba yín ti kọ̀ mí sílẹ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn tí wọ́n ń bọ, tí wọ́n ń sìn, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọn kò sì tẹ̀lé òfin mi mọ́.
12 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti ṣe búburú ju ti àwọn baba yín lọ. Ní bí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ṣe ń tẹ̀lé ọkàn líle rẹ̀, dípò èyí tí ó yẹ kí ẹ fi gbọ́ tèmi.
13 Èmi yóò gbé yin kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí bàbá yín tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ rí, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti máa sìn Ọlọ́run kékèké ní ọ̀sán àti òru nítorí èmi kì yóò fi ojúrere wò yín.’
14 “Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá,” ni Olúwa wí, “tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láàyè Olúwa ń bẹ Ẹni tí ó mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Éjíbítì.’
15 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Bí Olúwa ṣe wà nítòótọ́ tí ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti ní gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó ti lé wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò dá wọn padà sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn
16 “Ṣùgbọ́n báyìí, Èmi yóò ránsẹ́ sí àwọn apẹja púpọ̀,” ni Olúwa wí. “Wọn ó sì dẹ wọ́n lẹ́yìn èyí yìí èmi yóò ránsẹ́ sí àwọn ọdẹ púpọ̀, wọn yóò dẹ wọ́n lórí gbogbo òkè ńlá àti òkè gíga, àti ní gbogbo pálapàla àpáta.
17 Ojú mi wà ní gbogbo ọ̀nà wọn, wọn kò pamọ́ fún mi bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò farasin lójú mi.
18 Èmi yóò san ẹ̀san ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn ní ìlọ́poméjì, nítorí wọ́n ti ba ilẹ̀ mi jẹ́ pẹ̀lú àwọn ère wọn aláìlẹ́mìí, wọ́n sì ti kún ohun ìní mi pẹ̀lú ẹ̀gbin òrìṣà wọn.”
19 Olúwa, alágbára àti okun miẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njúÁà! àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá látiòpin ayé wí pé,“Àwọn baba ńlá wa kò ní ohunkan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìsà,ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀.
20 Ṣé àwọn ènìyàn lè dá Ọlọ́runfún ara wọn bí? Bẹ́ẹ̀ ni,ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí kì í ṣe Ọlọ́run.”