1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Éjíbítì ní Mígídò, Táfánásì àti Mémífísì àti ní apá òkè Íjíbìtì:
2 “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Wo ibi tí mo mú bá Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ìlú Júdà. Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun.
3 Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀.
4 Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, ‘Má ṣe àwọn ohun búburú tí èmi kò fẹ́.’
5 Ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ láti fi ọkàn si. Wọn kò sì yípadà kúrò nínú búburú wọn tàbí dáwọ́ ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà dúró.
6 Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Júdà àti òpópó Jérúsálẹ́mù àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí.
7 “Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí: Kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Júdà ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan?
8 Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lu ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Éjíbítì, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè ayé gbogbo.
9 Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn bàbá ńlá yín àti àwọn Ọba; àwọn ayaba Júdà, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Júdà àti ní òpópó Jérúsálẹ́mù?
10 Láti ìgbà náà sí àkókò yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ tàbí fi ìtẹ́ríba hàn tàbí kí wọn ó tẹ̀lé òfin àti àṣẹ tí mo pa fún un yín àti àwọn baba yín.
11 “Fún ìdí èyí, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì wí: Mo ti pinnu láti mú ibi wá sí orí yín àti láti pa Júdà run.
12 Èmi yóò sì mú àwọn èérún tí ó kù ní Júdà, tí wọ́n ṣetán láti lọ Éjíbítì. Wọn yóò ṣubú pẹ̀lú idà tàbí kí wọn kú pẹ̀lú ìyàn láti orí ọmọdé títí dé àgbà ni wọn yóò kú láti ọwọ́ ìyàn tàbí idà. Wọn yóò di ẹni ìfiré àti ìparun, ẹni ẹ̀kọ̀ àti ẹni ẹ̀gàn.
13 Èmi yóò fi ìyà jẹ ẹni tí ó bá ń gbé ní Éjíbítì pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn bí mo ṣe fi ìyà jẹ Jérúsálẹ́mù.
14 Kò sí èyí tí ó kéré jù nínú Júdà tí ó kù, tí ó ń gbé ilẹ̀ Éjíbítì tí yóò sá àsálà padà sórí ilẹ̀ Júdà, èyí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti padà sí, àti láti máa gbé; àyàfi àwọn aṣàtìpó mèlòó kan.”
15 Lẹ́yìn èyí, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ẹ bá mọ̀ pé, ìyàwó wọn sun tùràrí sí àwọn òrìṣà pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó bá wá àwọn ènìyàn púpọ̀, pàápàá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní òkè àti ìsàlẹ̀ Éjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni a wí fún Jeremáyà.
16 “Wọn sì wí pé: Àwa kò ní fetísílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o bá bá wa sọ ni orúkọ Olúwa.
17 Dájúdájú; à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe: A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run; à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn Ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ni àwọn ìgboro Jérúsálẹ́mù. Nígbà naà àwa ní ounjẹ púpọ̀ a sì ṣe rere a kò sì rí ibi
18 Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí a ti dáwọ́ tùràrí sísun sí ayaba ọrun sílẹ̀ àti láti da ẹbọ ohun mímu fún un, àwa ti ṣaláìní ohun gbogbo, a sì run nípa idà àti nípa ìyàn.”
19 Obìnrin náà fi kun-un pé, “Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rúbọ si; ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ?”
20 Wàyí o, Jeremáyà sọ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, ọkùnrin àti obìnrin, tí wọn sì ń dáhùn pé,
21 “Ṣe Ọlọ́run kò rántí ẹbọ sísun ní ìlú Júdà àti àwọn ìgboro Jérúsálẹ́mù láti ọ̀dọ̀ rẹ àti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá rẹ, àwọn Ọba àti àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn ìlú.
22 Nígbà tí Ọlọ́run kò lè fi ara da ìwà búburú yín àti àwọn nǹkan ìbínú gbogbo tí ẹ ṣe, ilẹ̀ yín sì di ohun ìfiré àti ìkọ̀sílẹ̀, láìsí olùgbé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà lónìí.
23 Nítorí pé ẹ ti sun ẹbọ, tí ẹ sì ti ṣẹ̀ sí Olúwa àti pé ẹ kò gbọ́ràn síi lẹ́nu, àti pé ẹ kò sì tẹ̀lé òfin rẹ̀ àti àwọn àṣẹ. Ibi náà yóò wá sórí rẹ àti bí o ṣe ríi.”
24 Nígbà náà ni Jeremáyà dáhùn pẹ̀lú obìnrin náà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ọmọ Júdà tí ó wà ní Éjíbítì.
25 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Ìwọ àti àwọn Ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ lórí sísun tùràrí àti dída ọtí sí orí ère ayaba ọ̀run ṣẹ.’“Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ.
26 Ṣùgbọ́n gbọ ọ̀rọ̀ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Éjíbítì, mo gégùn-ún: ‘Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi,’ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ‘wí pé, kò sí ẹnikẹ́ni láti Júdà tí ń gbé ibikíbi ní Éjíbítì ni tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra. “Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láàyè.”
27 Nítorí náà, mò ń wò wọ́n bí i fún ìparun, kì í ṣe fún rere. Àwọn Júù tí ó wà ní Éjíbítì yóò parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi parun.
28 Àwọn tí ó bá sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìparun idà àti pípadà sí ilẹ̀ Júdà láti Éjíbítì yóò kéré níye. Gbogbo àwọn tí ó bá kú ní ilẹ̀ Júdà, tí ó wá gbé ilẹ̀ Éjíbítì yóò mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò dúró yálà tèmi tàbí ti yín.
29 “ ‘Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún un yín pé èmi yóò fi ìyà jẹ yín níbi tí Olúwa ti sọ láti lè jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìjìyà mi tí mo sọ pé ẹ̀ ó jẹ yóò ṣẹ.’
30 Báyìí ni Olúwa wí: ‘Èmi yóò fi Fáráò Hópírà Ọba Éjíbítì lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́, èyí tí ó lè pa ayé rẹ́; gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekáyà Ọba Júdà lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lọ́wọ́ ọ̀tá tó ń lépa ẹ̀mí rẹ̀.’ ”