1 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:
2 “Lọ kéde sí etí ìgbọ́ àwọn Jérúsálẹ́mù:“ ‘Mo rántí ìfarasìn ìgbà èwe rẹ,gẹ́gẹ́ bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ mi bí i wúndíá àti bí o ṣe tẹ̀lé mi nínú aṣálẹ̀ àti nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.
3 Ísírẹ́lì jẹ́ mímọ́ sí Olúwa, àkọ́kọ́èṣo ìkórè rẹ̀, gbogbo ẹnikẹ́ni tí óbá jẹ run ni a ó dá lẹ́bi, ìpọ́njúyóò dé bá wọn,’ ”bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.
4 Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jákọ́bùàti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Ísírẹ́lì.
5 Báyìí ni Olúwa wí:“Irú àwọn àìṣedédé wo ni baba yín rí nínú mi?Tí wọ́n fi jìnnà sími? Wọ́n tẹ̀léàwọn òrìṣà tí kò jámọ́ nǹkan kanàwọn fúnra wọn sì jẹ́ ènìyàn yẹpẹrẹ.
6 Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà tí ó mú wọn,jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì, tí ó mú wala ihà já, tí ó mu wọn la àárin àwọnaṣálẹ̀ àti òkè láàrin ìyàngbẹ ilẹ̀àti òkùnkùn wá ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́nikò ti rìnrìn-àjò, tí ẹníkẹ́ni kò sì gbé?’
7 Mo mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá láti máajẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀, ẹ̀yin sì wá, ẹ sìba ilẹ̀ náà jẹ́, ẹ sì mú àwọnohun ogún mi di ohun ìríra.
8 Àlùfáà kò bèèrè wí pé níbo ni Olúwa wà? Àwọn tí ń ṣiṣẹ́pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọnolórí wọn sì gbógun sí mi,àwọn wòlíì sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nípaòrìṣà báálì, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọnòrìṣà yẹpẹrẹ.
9 “Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ́kan síi,”ni Olúwa wí.“Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ
10 Rékọjá sí ẹkùn kan kítímì, kí osì wò ó, ránṣẹ́ sí kéda, kí o sìwò ó dáradára, wò ó kí ẹ sìwò ó bí irú nǹkan báyìí báwà níbẹ̀ rí?
11 Orílẹ̀ èdè kan há á pa Ọlọ́run rẹ̀ dà?(Síbẹ̀, wọn kì í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run)àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.
12 Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́sẹ̀ méjìkí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,”ni Olúwa wí.
13 “Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́sẹ̀, méjìWọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmiorísun omi ìyè, wọ́n sì tiwọ àmù, àmù fífọ́ tí kò lègba omi dúró.
14 Ísírẹ́lì há á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ẹrú nípa ìbí? Kí ló há adé tí ó fi di ìkógun?
15 Àwọn kìnnìún ké ramúramúwọ́n sì ń bú mọ́ wọnwọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfòÌlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sìti di ìkọ̀sílẹ̀.
16 Bákan náà, àwọn ọkùnrinMémífísì àti Táfánésìwọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.
17 Ẹ̀yin kò há a ti fa èyí sóríara yín nípa kíkọ Ọlọ́run sílẹ̀nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?
18 Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Éjíbítìláti lọ mu omi ní Síhórì?Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Àsíríàláti lọ mu omi ni odò Yúfúrátè náà
19 Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yínÌpàdàṣẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wímọ̀ kí o sì ríi wí pé ibi àtiohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹnígbà tí o ti kọ Ọlọ́run ọmọogun sílẹ̀, ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,”ni Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí.
20 “Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgàrẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’Lóòtọ́, lórí gbogbo òkè gíga niàti lábẹ́ igi tí ó tàn kálẹ̀ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.
21 Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bíàjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá,Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí midi àjàrà búburú àti aláìmọ́?
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódàtí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹàbàwọ́n àìṣedéédéé rẹ sì ń bọ̀ níwájú mi,”ni Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí.
23 “Báwo ni o ṣe le lọ sọ pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́;Èmi kò ṣáà tẹ̀lé àwọn Báálì’?Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì;wo ohun tí o ṣe.Ìwọ jẹ́ abo ìbákasíẹ̀tí ń sá sí ìhín sọ́hùn ún.
24 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ tí ń gbé ihàtí ń fa ẹ̀fúùfù nínú ìfẹ́ inú rẹ̀ta ni ó le è mu dúró ní àkókò rẹ̀?Kí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ílé e má ṣe dára wọn lágaranítorí wọn ó ò rí ní àkókò oṣù rẹ̀.
25 Má ṣe sáré títí ẹṣẹ̀ yín yóò fi wà ní ìhòòhò,tí ahọ́n yín yóò sì gbẹ.Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Kò nílò!Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì,èmi yóò sì lépa wọn lọ.’
26 “Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójú ti olènígbà tí a bá mú u,bẹ́ẹ̀ náà ni ilé Ísírẹ́lìyóò gba, àwọn ìjòyè wọn,àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú.
27 Wọn sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni bàbá mi,’àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi, wọn kò kọojú sí mi ṣíbẹ̀ nígbà tí wọ́nbá wà nínú ìṣòro, wọn yóòwí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’
28 Níbo wá ni àwọn Ọlọ́run (kékeré) tíẹ ṣe fúnra yín há a wà?Jẹ́ kí wọn wá kí wọn sìgbà yín nígbà tí ẹ báwà nínú ìṣòro! Nítorí péẹ̀yin ní àwọn Ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́bí ẹ ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Júdà.
29 “Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí?Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,”ni Olúwa wí.
30 “Nínú aṣán mo fìyà jẹ àwọnènìyàn yín, wọn kò sì gbaìbáwí, idà yín ti pa àwọnwòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bíkìnnìún tí ń bú ramúramù.
31 “Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsí ọ̀rọ̀ Olúwa:“Àbí ilẹ̀ ńlá olókùnkùnkí ló dé tí àwọn ènìyàn mi ṣesọ wí pé, ‘A ní àǹfààní látimáa rìn kiri? A kò sì ní wá sọ́dọ̀ rẹ mọ́?’
32 Wúndíá ha le gbàgbé ohunọ̀ṣọ́ rẹ̀ bí, tàbí ìyàwó ha le gbàgbé ohunọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀? Síbẹ̀, àwọnènìyàn mi ti gbàgbé mi ní ọjọ́ àìníye.
33 Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípaọ̀rọ̀ ìfẹ́! Àwọn obìnrin tí ó tilẹ̀burú yóò kẹ́kọ̀ọ́ láti àwọn ọ̀nà rẹ
34 Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n bá ẹ̀jẹ̀àwọn talákà aláìṣẹ̀bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ká wọnníbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé
35 Ṣíbẹ̀ nínú gbogbo èyíìwọ sọ wí pé, ‘Èmi jẹ́ aláìsẹ̀kò sì bínú sími.’Èmi yóò ṣe ìdájọ́ mi lórí rẹnítorí pé ìwọ sọ pé, ‘Èmi kò tí ìdẹ́sẹ̀.’
36 Kí ló dé tí o fi ń lọ káàkiriláti yí ọ̀nà rẹ padà?Éjíbítì yóò dójú tì ọ́gẹ́gẹ́ bí i ti Ásíríà