Jeremáyà 32 BMY

Jeremáyà Ra Pápá Kan

1 Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọdún kẹwàá sédékáyà Ọba Júdà, èyí tí ó jẹ́ ọdún kejìdínlógún ti Nebukadinésárì.

2 Àwọn ogun Ọba Bábílónì ìgbà náà há Jérúsálẹ́mù mọ́. A sì ṣé wòlíì Jeremáyà mọ́ inú túbú tí wọ́n ń sọ́ ní àgbàlá ilé Ọba Júdà.

3 Nítorí Sedekáyà Ọba Júdà ti há a mọ́lé síbẹ̀; pé, “Kí ló dé tí ìwọ fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ báyẹn? Tí o sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Èmi ń bọ̀ wá fi ìlú yìí fún Ọba Bábílónì, tí yóò sì gbà á.

4 Sedekáyà Ọba Júdà kò lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn Kálídéà, ṣùgbọ́n à ó mú fún Ọba Bábílónì, yóò sì bá sọ̀rọ̀ ní ojúkojú; yóò sì rí pẹ̀lú ojú rẹ̀.

5 Yóò mú Sedekáyà lọ sí Bábílónì tí yóò wà títí èmi yóò fi bẹ̀ ọ́ wò ni Olúwa wí. Tí ẹ̀yin bá bá àwọn ará Kálídéà jà, ẹ̀yin kì yóò borí wọn.’ ”

6 Jeremáyà wí pé, “ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

7 Hánámélì ọmọkùnrin Sálúmù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò tọ̀ ọ́ wá pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì; nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó sún mọ́ wọn, ẹ̀tọ́ àti ìṣe rẹ ní láti rà á.’

8 “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ, ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì tí ó wà ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì, èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ.’“Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni èyí.

9 Bẹ́ẹ̀ ni; èmi ra pápá náà ní Ánátótì láti ọwọ́ Hánámélì ọmọ ẹ̀gbọ́n mi. Ó sì wọn ìwọn ṣékélì àti fàdákà mẹ́tadínlógún fún un.

10 Mo fọwọ́ sínú ìwé, mo sì dì í pa. Mo pe ẹlẹ́rìí síi, mo sì wọn fàdákà náà lórí òṣùwọ̀n.

11 Mo mú ìwé tí mo fi rà á, èyí tí a di pa nípa àṣẹ àti òfin wa, àti èyí tí a kò lẹ̀.

12 Èmi sì fi èyí fún Bárúkì ọmọkùnrin ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ti fi ọwọ́ sí ìwé àti ní ojú àwọn Júù gbogbo tí wọ́n jókòó ní àgbàlá túbú.

13 “Ní ojú wọn ni èmi ti pàṣẹ fún Bárúkì pé:

14 Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; mú àwọn ìwé tí a fi rà á wọ̀nyí, àti èyí tí a lẹ̀ àti èyí tí a kò lẹ̀, kí o wá gbé wọn sínú ìkòkò amọ̀, kí wọn ó lè wà ní ọjọ́ púpọ̀.

15 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; àwọn ilẹ̀, pápá àti ọgbà àjàrà ni à ó tún rà padà nílẹ̀ yìí.

16 “Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé rírà náà fún Bárúkì ọmọkùnrin Néráyà, mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé:

17 “Áà! Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbogbo, ìwọ tí o dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú títóbi agbára rẹ àti gbogbo ọ̀rọ̀ apá rẹ. Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ láti ṣe.

18 O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹ̀gbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn. Ọlọ́rùn títóbi àti alágbára, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ.

19 Títóbi ni iṣẹ́ rẹ, agbára sì ni ìṣe rẹ. Ojú rẹ sí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọkùnrin, ó sì fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti ìwà rẹ̀.

20 O ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá ní Éjíbítì. O sì ń ṣe é títí di òní ní Ísírẹ́lì àti lára ọmọ ènìyàn tí ó sì ti gba òkìkí tí ó jẹ́ tìrẹ.

21 O kó àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ jáde láti Éjíbítì pẹ̀lú àmì àti ìyanu nínú ọwọ́ agbára àti nína apá rẹ pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá.

22 Ìwọ fún wọn nílẹ̀ yìí, èyí tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn; ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.

23 Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ohun tí o paláṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn.

24 “Wò ó, bí àwọn ìdọ̀tí ṣe korájọ láti gba ìlú. Nítorí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, sì fi ìlú lé ọwọ́ àwọn ará Kálídéà tí ń gbógun tì wọ́n. Ohun tí ìwọ sọ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i.

25 Ṣíbẹ̀ à ò fi ìlú náà fún àwọn ará Kálídéà. Ìwọ Olúwa Ọba sọ fún mi pé, ‘Ra pápá náà pẹ̀lú owó fàdákà, kí o sì pe ẹlẹ́rìí.’ ”

26 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá pé:

27 “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run gbogbo ẹran ara. Ǹjẹ́ ohun kan há a ṣòro fún mi bí?

28 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: Èmi ṣetan láti fi ìlú yìí fún àwọn ará Kálídéà àti fún Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ẹni tí yóò kó o.

29 Àwọn ará Kálídéà tí ó ń gbógun tí ìlú yóò wọ ìlú. Wọn ó sì fi iná sí ìlú; wọn ó jó o palẹ̀ ní ọ̀nà ilé tí àwọn ènìyàn ti ń mú mi bínú, tí wọ́n ń rúbọ tùràrí lórí pẹpẹ fún Báálì ti wọn sì ń da ẹbọ òróró fún Ọlọ́run mìíràn.

30 “Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àti Júdà kò ṣe ohun kankan bí kò ṣe ibi lójúmi láti ìgbà èwe wọn. Nítorí àwọn ọmọ Isreli ti fi kìkì iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n mú mi bínú ni Olúwa wí

31 Láti ọjọ́ tí wọ́n ti kọ́ ọ, títí di àkókò yìí ni ìlú yìí ti jẹ́ ohun ìbínú àti ìyọnu fún mi tó bẹ́ẹ̀ tí èmi yóò fà á tu kúrò níwájú mi.

32 Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àti àwọn ènìyàn Júdà ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ìbàjẹ́ ni wọn tí wọ́n ṣe. Àwọn Ísírẹ́lì, Ọba wọn àti gbogbo ìjòyè, àlùfáà àti wòlíì, àwọn ọkùnrin Júdà àti àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù.

33 Wọ́n kọ ẹ̀yìn sími, wọ́n sì yí ojú wọn padà. Èmi kọ̀ wọ́n, síbẹ̀ wọn kò fetísílẹ̀ láti gbọ́ ẹ̀kọ́ tàbí kọbiara sí ìwà ìbàjẹ́.

34 Wọ́n kó òrìṣà ìríra wọn jọ sí inú ilé tí wọ́n fi orúkọ mi pè, wọ́n sì sọ́ di àìmọ́.

35 Wọ́n kọ́ ibi gíga fún Báálì ní àfonífojì Hínómù láti fi ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin rúbọ sí Mólékì. Èmi kò páláṣẹ, fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò wá sí ọkàn mi pé kí wọ́n ṣe ohun ìríra wọ̀nyí tí ó sì mú Júdà ṣe.

36 “Ìwọ ń sọ̀rọ̀ nípa ti ìlú yìí pé, ‘Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn ni à ó fi wọ́n fún Ọba Bábílónì,’ ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nì yìí:

37 Èmi ó kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti lé wọn kúrò ní ìgbà ìbínú àti ìkáàánú ńlá mi. Èmi yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀ yìí; èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó máa gbé láìléwu.

38 Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.

39 Èmi ó fún wọn ní ọkàn kan àti ìṣe kí wọn kí ó lè máa bẹ̀rù mi fún rere wọn àti fún rere àwọn ọmọ wọn tí ó tẹ̀lé wọn.

40 Èmi ò bá wọn dá májẹ̀mú ayérayé, èmi kò ní dúró láti ṣe rere fún wọn: Èmi ó sì jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù mi, wọn kì yóò sì padà lẹ́yìn mi.

41 Èmi ó yọ̀ nípa ṣíṣe wọ́n ní rere, èmi ó sì fi dá wọn lójú nípa gbíngbìn wọ́n sí ilẹ̀ yìí tọkàntọkàn mi.

42 “Nítorí bayìí ni Olúwa wí: Gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú gbogbo ibi ńlá yìí wá sórí àwọn ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó mú gbogbo rere tí èmi ti sọ nípa ti wọn wá sórí wọn.

43 Lẹ́ẹ̀kan síi, pápá yóò di rírà ní ilẹ̀ yìí tí ìwọ ti sọ pé, ‘Ohun òfò ni tí kò bá sí ọkùnrin tàbí àwọn ẹran, nítorí tí a ti fi fún àwọn ará Bábílónì.’

44 Wọn ó fi owó fàdákà ra oko, wọn yóò fi ọwọ́ sí ìwé, wọn ó dí i pa pẹ̀lú ẹlẹ́rìí láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì àti ní ìlú kékèké tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká àti ní ìlú Júdà àti ní ìlú ọwọ́ òkè orílẹ̀ èdè ní ìhà gúṣù olókè ilẹ̀ àti ní Gúsù, nítorí èmi ó mú ìgbékùn wọn padà wá, ni Olúwa wí.”