Jeremáyà 8 BMY

1 “ ‘Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, wọn yóò mú egungun àwọn ọba Júdà àti egungun àwọn ijoye, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù kúrò nínú ibojì.

2 A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dà bí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀.

3 Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí.’

Ẹ̀ṣẹ̀ Àti Ìjìyà

4 “Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀wọn kì í padà dìde bí? Nígbà tíènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ,kì í yí padà bí?

5 È é ṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyífi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kílódé tí Jérúsálẹ́mùfi yà kúrò ní gbogbo ìgbà?Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn, wọ́n kọ̀ láti yípadà.

6 Mo ti fetí sílẹ̀ dáradára, wọnkò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tóronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀,kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkùń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.

7 Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbàtirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèémọ àkókò ìsípòpadà wọn. Ṣùgbọ́n àwọnènìyàn mi kò mọ ohun tí Ọlọ́run wọn fẹ́.

8 “ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n,nítorí a ní òfin Olúwa,” nígbàtí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọnakọ̀wé ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn

9 Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n, a ó dàwọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn.Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa. Irú ọgbọ́nwo ló kù tí wọ́n ní?

10 Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fúnàwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọnfún àwọn ẹlòmíràn láti èyí tó kéréjù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọnni èrè àjẹjù ń já lẹ́nu; àwọn wòlíìàti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn.

11 Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́bí èyí tí kò jinlẹ̀.“Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí,nígbà tí kò sí àlàáfíà.

12 Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn? Bẹ́ẹ̀ kọ́,wọn kò ní ìtìjú rárá; wọn kò tilẹ̀ mọbí wọ́n ti ṣe ń mí oru-ìtìjú. Nítorí náàwọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú,a ó sì fà wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá ń fiìyà jẹ wọ́n,ni Olúwa wí.

13 “ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúròni Olúwa wí.Kì yóò sí èṣo lórí igi àjàrà,kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀.Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò.’ ”

14 “È é ṣe tí a fi jòkó ní ibí yìí?A kó ara wa jọ!Jẹ́ kí a sá lọ sí ìlú olódi kí o sì ṣègbé síbẹ̀.Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run wa tipinnu pé a ó ṣègbé. Yóò sì fúnwa ní omi onímájèlé láti mu, nítorí àwa ti sẹ̀ sí i.

15 Àwa ń retí àlàáfíà, kò síire kan tí ó wá ní ìgbà ìmúláradábí kò ṣe ìpayà nìkan.

16 Ìró ìfọnmú ẹsin àwọn ọlọ̀tẹ̀ là ńgbọ́ láti Dánì yíyan àwọn akọ ẹsinmú gbogbo ilẹ̀ wárìrì. Wọ́n wá látipa ilẹ̀ náà run, gbogbo ohun tówà níbẹ̀, ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀.”

17 “Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró síàárin yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa orówọn, yóò sì bù yín jẹ,”ni Olúwa wí.

18 Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mirẹ̀wẹ̀sì nínú mi.

19 Fetí sí igbe àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ tó jìn:“Olúwa kò ha sí ní Síóní bí?Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?”“È é ṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn, pẹ̀lú àwọnòrìṣà àjòjì tí wọn kò ní láárí?”

20 “Ìkóórè ti ré kọ́ja, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti paríṣíbẹ̀, a kò gbà wá là.”

21 Níwọ̀n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run,èmi náà run pẹ̀lú, mo sọ̀fọ, ìrora sì mú mi káká.